Lẹ́yìn ìròyìn pé káláìsàn ó máa san ẹgbẹ̀rún kan owó iná, ẹlẹ́yinjú àánú fi ẹgbẹ̀rún kan lítà epo dísù ránṣẹ́ sí iléèwòsàn UCH

Iwaju ileewosan nla UCH

Oríṣun àwòrán, other

Ni ọjọ Aje ni ileeṣẹ BBC News Yoruba gbe iroyin nipa ileewosan nla UCH nibi ti iwe akọranṣẹ labẹle kan ti lu sita .

Aṣẹ inu lẹta naa lo ni pe awọn alaṣẹ ileewosan naa fé ki awọn aláìsàn tó bá wà ní ilé ìwòsàn náà óò máa san ẹgbẹ̀rún kan náírà ní ojoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí owó iná.

Iroyin to n tẹ BBC News Yoruba lọwọ bayii n sọ pe eeyan kan to ri apinka iroyin naa to lu ori ayelujara pa lanaa ni eyi ti wọn fi ranṣẹ sii lati ilẹ okeere ti gbe owo kalẹ fun rira ẹgbẹrun kan lita epo disu lati fi tan ina ni ileewosan nla naa.

Alukoro ileewosan nla UCH, Ogbeni Toye Akinrinọla ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ẹlẹyinju aanu kan ti orukọ rẹ n jẹ Họnọrebu Lanre Laoshe se eto aanu naa.

O ni pe Laoshe lo pe ileewosan naa to si sọ fun wọn pe oun mọ ipenija ti irufẹ ileewosan nla bii ti UCH lee maa dojukọ laarin bi nnkan ṣe n lọ kaakiri bayii.

O ni Họnọrebu Laoshe lo wa gbe owo kalẹ pe ki wọn fi ra ẹgbẹrun kan lita disu fun elo ileewosan nla naa.

Atẹjade UCH lori ẹlẹyinjuaanu to fi disu ranṣẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ta ni Ẹlẹyinju aanu to gbe disu ẹgbẹrun kan lita kalẹ fun elo awọn alaisan ni UCH?

Ninu atẹjade kan ti awọn alaṣẹ ileewosan nla UCH nilu Ibadan fi sita, dokita agba nibẹ  Ọjọgbọn Jesse Abiọdun Ọtẹgbayọ kan sara si ẹlẹyinju aanu naa.

O pe orukọ rẹ ni Họnọrebu Lanre Laoshe lati ilu Eko fun itọrẹ aanu lati ran ileewosan nla naa lọwọ.

Gẹgẹ bi ohun ti Ọjọgbọn Ọtẹgbayọ kọ, Họnọrebu Laoshe sọ pe:

“Mo wa ninu ẹgbẹ ikanni ori 'Whatsapp' kan nibi ti iroyin kan ti jade lori ile iwosan UCH pe awọn alaisan yoo maa san ẹgbẹrun kan Naira owo ina.

"Mo kaanu gidi fun ileewosan UCH nitori pe mo woo pe ki wọn to le fọkan pọ sori igbesẹ bẹẹ a jẹ wi pe nnkan ti kọja ẹmi wọn ni.

"Mo sọ fun awọn akẹgbẹ mi lori ikanni naa pe dipo bibu ẹnu atẹ lu ileewosan UCH, o yẹ ki a wa ọna lati ran ileewosan naa lọwọ ni.

Ẹlẹyinju aanu to fun UCH ni epo disu

Oríṣun àwòrán, University College Hospital, Ibadan/facebook

Honorebu naa ni pe: “Ogo orilẹ-ede Naijiria ni UCH,

Ogo ajumọni gbogbo wa ni ileewosan nla UCH jẹ.

Eyi ni mo fi pinnu lati gbe disu ẹgbẹrun lita kan silẹ gẹgẹ bi iwọnba igbesẹ majẹ ko bajẹ temi lati koju ipenija ipese ina mọnamọna ni ileewosan naa.”

Ọjọgbọ̀n Ọtẹgbayọ ni ki agogo marun un irọlẹ ọjọ Aje to lu ni epo disu ti Họnọrebu Laoshe ṣeleri ti de ikawọ awọn alaṣẹ ileewosan naa.

Alaye lori iwe iwe akọranṣẹ labẹle ‘Memo’ lori sisan ẹgbẹrun kan owo ina wa?

Aworan iwe akọranṣẹ labẹnu

Oríṣun àwòrán, other

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, alukoro ileewosan nla UCH, Ọgbẹni Akinrinọla ṣalaye pe nigba ti wahala ipese ina fẹ pin ileewosan naa lẹmi lawọn alaṣẹ ileewosan naa fi gbe ipade dide nibi ti aba orisiirisii ti jẹyọ lori ọna ati wa ojuutu si iṣoro ipese ina.

Awọn miran n gbamoran orisii bii eyi fun awon alase UCH lati fi wa ojutu si isoro naa:

1. Mimu ki awọn alaisan to wa nibẹ o san ẹgbẹrun kan Nairia owo ina

2. Lilọ kaakiri ori ayelujara lati sọ nipa iṣoro yii fun awọn oninudidun ọlọrẹ ti o ba lee ṣe ileewosan naa laanu

3. Tabi fifi ẹgbẹrun kan owo ina sisan naa sori iye owo ti olukuluku awọn alaisan to ba wa sileewosan naa yoo maa san, ṣugbọn wọn ko ni jẹ ki wọn mọ.

Pelu ọpọ imoran mii lo n jade bayii

Bakan naa ni ọpọ eeyan n sọrọ si ijọba Naijiria lori pe abuku ijọba to wa lori aleefa ni pe ileewosan Fasiti akọkọ ni Naijiria ko ri owo fi pese ina Oba fun alaisan lasiko yii.

Awọn miran tun sọrọ si awọn alaṣẹ pe ajẹbanu wọn ti pọju ninu awon oloselu orilẹede yii.

Amọṣa, ko tii si eyikeyi ninu awọn alaisan to wa nileewosan naa to tii san owo naa titi di bi a ṣe n sọrọ yii.

Se lootọ ni pe ẹgbẹrun ogun eeyan lo n wa ni UCH lojumọ?

Iwaju ileewosan nla UCH

Oríṣun àwòrán, other

Ni kete ti iroyin naa jade lọjọ Aje ni awọn ọmọ Naijiria ti n ba ileewosan naa ṣi iye ti owo naa yoo maa ja si fun wọn lojumọ.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe iye awọn alaisan to n wọ ileewosan naa lojumọ ko din ni ẹgbẹrun lọna ogun lawọn kan n sọ pe yoo to biliọnu kan naira ti wọn yoo maa ri rejọ lori owo epo disu naa.

Amọṣa, nigba ti BBC News Yoruba gbọ ọrọ lẹnu alukoro ileewosan naa, o ni gbogbo aye bẹẹdi to wa lati gba alaisan si ni ileewosan naa ko ju ẹgbẹrun kan o le igba lọ (1, 200).

O ṣalaye pe ko si ileewosan kankan lagbaye to le e ni aaye lati gba alaisan ẹgbẹrun lọna ogun lojumọ.

O fi kun un pe gbogbo ohun to ṣokunfa wahala yii ko ju bi ileeṣẹ apinna ọba IBEDC ṣe n kuna lati pese ina fun ileewosan naa bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.

O fi kun un pe nnkan bii aadọta si adoorin rin miliọnu lawọn alaṣẹ ileewosan naa nsan loṣu fun ina ọba ti wọn si tun maa n na bii ogun miliọnu miran lati fi ra epo disu si ẹrọ amunawa gbogbo ti wọn n lo nibẹ.

Àwọn aláìsàn yóò máa san #1,000 lójúmọ̀ fún owó iná - Ilé ìwòsàn UCH, Ibadan

Ilé ìwòsàn UCH, Ibadan

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn University College Hospital, UCH, Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ti ní àwọn aláìsàn tó bá wà ní ilé ìwòsàn náà yóò máa san ẹgbẹ̀rún kan náírà ní ojoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí owó iná.

Wọ́n ní èyí jẹ́ láti mú àdínkù bá ìpèníjà tí ilé ìwòsàn náà ń kojú lórí sísan owó iná ọba àti ríra dísù sínú gẹnẹrétọ̀ tí wọ́n fi ń tan iná ní ilé ìwòsàn náà.

Nínú ìwé àkọránṣẹ́ lábẹ́lé lọ́jọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ní owó tó ń lé owó iná ọba àti bí dísù ṣe ń fi ojoojúmọ́ gbẹ́nu sókè si ló mú àwọn pinnu láti ní kí àwọn aláìsàn máa san owó iná tí wọ́n bá lò.

 Ìwé náà tí alákoso ilé ìwòsàn náà, Wole Oyeyemi buwọ́lu lórúkọ gíwà àgbà ilé ìwòsàn ọ̀hún ní ìgbésẹ̀ yìí yóò jẹ́ kí àwọn le pèsè ìwòsàn tó péye fún àwọn aláìsàn.

Bákan náà ló ní àwọn ti buwọ́lu ìpinnu nìyí.