Ẹ ò kójú òṣùwọ̀n láti tún Nàìjíríà ṣe, Ango Abdullahi sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Tinubu àti Atiku
Tinubu àti Atiku ò kójú òṣùwọ̀n láti tún Naijiria ṣe - Ango Abdullahi

Oríṣun àwòrán, A. Atiku/BAT
Ẹni to n ṣagbatẹru ẹgbẹ Northern Elders Forum, NEF, Ango Abdullahi ti sọ pe awọn oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC, Atiku Abubakar ati Bola Tinubu ko dantọ lati yanju iṣoro Naijiria.
O ni o ti le lọgbọn ọdun ti awọn agba oṣelu mejeji naa ti wa loke tente eto oṣelu Naijiria, amọ oun ko ro pe awọn ni ọna abayọ si iṣoro to n koju Naijiria.
Abdullahi lo sọ ọrọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin.
O fi kun pe o ṣeeṣe ki Ọjọgbọn Yemi Osinbajo le kajuẹ lati tun Naijiria ṣe.
O ni “A ko tii ri ọkunrin naa ti yoo tun Naijiria ṣe, awọn ti a ni lọwọ bayii ko kajuẹ.”
“Bawo ni ẹ ṣe le wo Tinubu ati Atiku sunsun ki ẹ wa sọ pe awọn ni yoo tun Naijiria ṣe?”
Abdullahi tẹsiwaju pe “Wọn ti wa ninu eto oṣelu lati nnkan bii ọdun marundinlọgbọn si ọgbọn ọdun, ki ni aṣeyọri wọn?”
Osinbajo, Kwankaso ati Obi le gbiyanju
Oloṣelu naa ni oun ni igabgbọ ninu Osinbajo lati tun Naijiria ṣe amọ awọn eeyan kan ko ni jẹ ko tọ ipo Aarẹ wo.
O ni “A ni awọn oloṣelu to dantọ bii Osinbajo amọ wọn ni jẹ ko de bẹ.”
Abdullahi ni lootọ ni oun ko mọ Peter Obi daadaa, amọ ọdọmọde ni, onisọwo ni, olori pipe si ni pẹlu.
Ni ti Kwakanso, o ni “Eeyan gidi ni, ọdọ si ni… ọlọpọlọ pipe ni pẹlu, lai ṣe aniani, o wa lara awọn eeyan ti ori wọn pe ti a ni.”
O pari ọrọ rẹ pe o yẹ ki awọn agbagba Naijiria jiroro lori bi atunṣẹ yoo ṣe de ba Naijiria ju ki wọn maa ba ara wọn ja lori ẹya tabi ẹkun to yẹ ko di Aarẹ lọdun to n bọ lọ.












