Ọkùnrin kan yìnbọn pa èèyàn mẹ́fà níbi ayẹyẹ òmìnira ‘4th of July’ nílùú Chicago

Highland Park shooting: Ọlọ́pàá ti ń wá ọkùnrin tó yìnbọn pa èèyàn mẹ́fà níbi ayẹyẹ òmìnira ‘4th of July’ ní Chicago

Highland Park shooting:

Oríṣun àwòrán, EPA

Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Amẹrika ti n wa ọkunrin kan to yinbọn pa eeyan mẹfa nibi ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ ominira 4th of July niluu Chicago.

Iroyin ni ori aja ile kan ni ọkunrin ọhun lugọ si ko to dana ibọn ya awọn eeyan ọhun.

Ayẹyẹ ominira naa, ti ọpọ eeyan n gbadun lo dede danuduro lẹyin ti wọn gbọ iro ibọn lera-lera.

O kere tan, eeyan mẹrinlelogun lo ti dero ile iwosan lẹyin iṣẹlẹ naa bayii.

Awọn ọlọpaa kede orukọ ẹni ti wọn fura si gẹgẹ bii Robert E Crimo III, to jẹ ẹni ọdun mejilelogun.

Wọn ni ṣe ni afurasi naa mọọmọ doju ija kọ awọn eeyan to n kopa ninu ayẹyẹ ominira naa lati ṣina ibọn fun wọn.

Iṣeju diẹ ti ayẹyẹ ọhun bẹrẹ ni Crimo dana ibọn ya awọn eeyan naa ni nnkan bii aago mẹwaa kọja iṣeju marundinlogun aarọ.

Highland Park shooting:

Ori aja ile kan ni afurasi ti yinbọn

Awọn ọlọpaa ni awọn gbagbọ pe ori aja ile kan to wa ni ayika ibi ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ naa ni afurasi ti yinbọn, lẹyin ti wọn ṣawari awọn ẹri pe ọta ibọn jabọ sibẹ.

Eeyan marun un lo ku lẹsẹkẹsẹ, nigba ti ẹlomiran papoda lasiko ti wọn n gbe lọ sile iwosan.

Gomina ilu naa, Nancy Rotering sọ pe ibanujẹ nla ni iṣẹlẹ naa jẹ fun ijọba oun.

O ni “Ọjọ ti a korajọ lati ṣajọyọ ayajọ ọjọ ominira wa lo pada ja si ọjọ ẹkun yii.”

4th of July jẹ ọjọ ti wọn ya sọtọ nilẹ Amẹrika lati maa ṣe iranti ọjọ ti ilẹ naa gba ominira lọwọ ilẹ Gẹẹsi lọdun 1776.