Atiku, PDP fẹ́ ṣàbèwò sí Wike láti parí aaáwọ̀ nínú ẹgbẹ́ náà

Aworan

Ajọ amuṣẹya ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti ṣetan lati gbe igbimọ kalẹ ti yoo ṣe ipade pẹlu gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike lọna ati wa abayọ si rogbodiyan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa.

Rogbodiyan naa ko ṣẹyin yiyan gomina ipinlẹ Delta gẹgẹ bi igbakeji oludije fun ipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu PDP.

Atiku Abubakar to jẹ oludije si ipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu PDP ni yoo tuko igbimọ ikọ alaafia naa.

Alaga Ajọ amuṣẹya ti ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnatọ Walid Jibril lo kede igbesẹ ti ẹgbẹ oṣelu naa n gbe lati pari aawọ to n ja ranyin nilẹ.

Jibril ni kete ti Atiku ati alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyorchia Ayu ba de lati oke okun ti wọn ti lọ sinmi ni igbesẹ naa yoo gberasọ.

O fikun un pe iṣẹlẹ aigboraẹniye ninu ẹgbẹ naa kọ oun ni ominu to si ti mu ki awọn oludije kọọkan maa fi aidunnu wọn han.

Bakan naa loni gomina Ifeanyi Okowa naa yoo wa ninu awọn ti yoo pẹtu si aawọ to n lọ lọwọ ni ẹgbẹ oṣelu PDP.

Awọn miran ti yoo tun wa ninu igbimo naa ni awọn gomina ni ẹgbẹ oselu PDP, awọn minisita ati awọn agbaagba ninu ẹgbẹ oṣelu naa ko ni gbẹyin.

Saaju ipade naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ paapaa ni ipinlẹ Rivers lati maṣe fi ẹgbẹ silẹ nitori ahesọ ti wọn n gbọ kaakiri.

O ni gbogbo wọn gbọdọ pawọpọ lati ripe gbogbo ọmọ ẹgbẹ ṣiṣẹ pọ fun ilọsiwaju ẹgbẹ oṣelu PDP ki ohun ti wọn n fẹ ba le tẹ wọn ni ọwọ.

Ọkan lara awọn to fi aidunnu wọn han ni gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayo Fayose to sọ wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti kuna nitori iha Guusu ni ipo aarẹ sun kan ti Atiku to bori ninu idibo abẹle si wa lati iha ariwa orilẹede Naijiria.