Fòpin sí ìjíròrò tí ò ń bá Kwankwaso ṣe – Àwọn alátìlẹyìn Peter Obi kìí nílọ̀

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ẹgbẹ́ àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party àti olùdíje sípò Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Peter Obi ti rọ̀ ọ́ láti ṣe ìdádúró gbogbo ìjíròrò tó ń lọ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigerian Peoples Party, NNPP.
Àrọwà yìí kò ṣẹ̀yìn ọ̀rọ̀ tí Kwankwaso sọ wí pé òun kò lè ṣe igbákejì Peter Obi láéláé tí àwọn bá gbà láti darapọ̀.
Bákan náà ni abẹ́ṣinkáwọ́ Kwankwaso, Buba Galadima nígbà tí òun náà ń sọ̀rọ̀ lórí ètò ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán Arise ní ẹgbẹ́ iṣu kọ́ ni iyán tí a bá ń sọ̀rọ̀ Kwankwaso àti Obi nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú.
Galadima ní kò ṣeéṣe kí Kwankwaso ṣe igbákejì fún Peter Obi nítorí Peter Obi ṣẹ̀ṣẹ̀ ní àwọn alátìlẹyìn ni àmọ́ Kwankwaso ti ń kó àwọn ènìyàn jọ láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn.
Àmọ́ nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ, ẹgbẹ́ àwọn alátìlẹyìn Peter Obi tí wọ́n pe ara wọn ní “Peter Obi Support Network” Onwuasoanya Jones ní kí Peter Obi àti Labour Party fi òpin sí gbogbo ohun tí wọ́n ń bá Kwankwaso jíròrò lé lórí.
Jones ní ó ti hàn wí pé ìbáṣepọ̀ àwọn olùdíje Obi àti Kwankwaso kò le rọgbọ.
Ó ní àwọn ọ̀rọ̀ tí Kwankwaso sọ lórí amóhùnmáwòrán fi hàn wí pé ọ̀rọ̀ ẹ̀yà ka lára ju mímú ìgbà ọ̀tun bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ.
Ó fi kun wí pé yàtọ̀ sí Kwankwaso fúnra rẹ̀, ó ní gbogbo àwọn abẹ́ṣinkáwọ́ Kwankwaso nínú ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP tí ń jẹ́ kó yé àwọn ọmọ Nàìjíríà wí pé gbogbo àwọn àyípadà ọ̀tun tí wọ́n ń pa oùngbẹ rẹ̀ kò kan àwọn.
Jones tẹ̀síwájú wí pé àwọn Kwankwaso àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ kò ṣetán láti ṣe agbátẹrù tàbí kópa nínú ètò òṣèlú tí yóò sọ Nàìjíríà di ibùgbé tó ṣe é gbé fún tẹrú tọmọ ní ọdún 2023.
Ó ṣàlàyé pé ó ti hàn gbangba gbàǹgbà pé ohun tó ń mú Peter Obi gbégbé ìbò láti di Ààrẹ Nàìjíríà kọ́ ló ń mú Kwankwaso díje àti pé ìmọ wọn lórí Nàìjíríà kò jọ ara wọn rárá.
Kwankwaso sàlàyé ìdí mẹ́rin tó fi kọ̀ láti se ìgbákejì Peter Obi ní 2023

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria People’s Party , Rabiu Kwankwaso ti ní òun kò le gbà láti ṣe igbákejì sípò Ààrẹ fún olùdíje kankan.
Kwankwaso ní ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ń lọ sí oko ìparun nìyẹn tí òun bá fi lè ṣe bẹ́ẹ̀.
Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kano ọ̀hún tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Gombe níbi tó ti lọ ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò ní ìpínlẹ̀ náà.
Ó ní gbogbo ìwọ̀nba òkìkí tí ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ní ni yóò wọ òòkùn tí òun bá gbà láti ṣe igbákejì ààrẹ fún ẹnikẹ́ni.
Ó ní lóòótọ́ ní ẹgbẹ́ òun àti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ti jọ ń jíròrò lórí bí àwọn yóò ṣe darapọ̀ àmọ́ ohun tó ń fa ìfàsẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ ta ni yóò ṣe ààrẹ?, ta ni yóò ṣe igbákejì?
Kwankwaso fi kun pé gbogbo ohun tí àwọn ti dìjọ ń sọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ló ń bọ́ sì déédé àyàfi ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ dání bí olùdíje sípò ààrẹ.
Ó fi kun pé èyí ló fàá tí àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ fi ń rò ó wí pé kí àwọn tẹ̀lé àwọn ìlànà kan bí i wíwo ọjọ́ orí, ipò tí àwọn ti dìmú tẹ́lẹ̀, bí àwọn ṣe ṣiṣẹ́ sí ní ọ́fíìsì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
“Àwọn ènìyàn inú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party kò ní fẹ́ gbà bẹ́ẹ̀ nítorí wọ́n gbàgbọ́ wí pé ẹkùn gúúsù ló yẹ kí Ààrẹ Nàìjíríà ti wá’.
“Tí mo bá sì gbà láti ṣe igbákejì ààrẹ, ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ma fọ́ pátápátá nítorí ohun tí a ti gbìn kalẹ̀ láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ni ẹgbẹ́ náà ṣì dúró lé lórí báyìí.”















