Èmi ò kábámọ̀ pé mo bá Abacha ṣiṣẹ́, ohun tó kù mí kù báyìí ni láti di ààrẹ kí n lè tú Nàìjíríà ṣe - Al- Mustapha

Aworan Al-Mustapha, amugbalẹgbẹ olori ijọba ologun ni Naijiria nigbakanri, ati ọga rẹ, Ọgagun agba Sani Abacha

Oríṣun àwòrán, other

Amugbalẹgbẹ fun olori ijọba ologun Naijiria nigba kan ri, Sani Abacha, Ọgagun, Hamza Al-Mustapha ti sọ pe oun ko kabamọ biba oloogbe Sani Abacha ṣiṣẹ rara, ṣugbọn oun ṣetan bayi lati di aarẹ funra oun lati dari ijọba orilẹede Naijiria.

Al-Mustapha ṣalaye yii lasiko to fi n kopa lori eto ileeṣẹ mohunmaworan abẹle kan ni Naijiria, Channels.

Al-Mustapha ni oludije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, AA.

O ni ẹnikẹni to ba ti darapọ mọ iṣẹ ologun ti mọ pe igbakigba ati ibikibi ni iṣẹ le gbe oun.

Amọṣa o ni igbe aye oun ko da lori ajọṣepọ oun ati ọga oun tẹlẹ, oloogbe Ọgagun agba Sani Abacha, ṣugbọn oun ṣetan lati fi aye oun sin orilẹede Naijiria sibẹ.

Gẹgẹ bi Ọgagun Al-Mustapha ṣe sọ, ifẹ oun si orilẹede Naijiria ati idagbasoke rẹ lo ṣi ọkan oun paya to si mu ki oun dide lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2023.

Al-Mustapha, amugbalẹgbẹ olori ijọba ologun ni Naijiria nigbakanri, Ọgagun agba Sani Abacha

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán, Al-Mustapha, amugbalẹgbẹ olori ijọba ologun ni Naijiria nigbakanri, Ọgagun agba Sani Abacha

“Mo pinnu lati jẹ hoo si ipe awọn ọmọ Naijiria, ati agba ati ewe kaakiri igun ariwa ati Gusu ti wọn pe mi lati dije.

“Ifẹ ti a ni si orilẹede yii pọ tobẹ gẹẹ to fi jẹ pe awọn to poruru nipa orilẹede yii nikan lo lee mọ awọn ipenija ti a koju lana, atawọn imọriri ipo ti a wa loni.”

Al-Mustapha ni awọn kan lee maa ro pe boya tori owo ati ọrọ to wa ni idi ipo aarẹ lo n mu ki oun fẹ dije, amọṣa oludije ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, AA naa jẹ ko di mimọ pe nnkan ti bajẹ pupọ lorilẹede Naijiria bayii, eyi to fi di dandan fun awọn olootọ ọmọ orilẹede Naijiria lati dide fun idagbasoke rẹ.