Ẹ tí sọ̀rọ̀, mo sí tí gbọ́ ọ̀rọ̀ tí PDP, Fayose sọ! – Atiku Fesi

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Oludije ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Atiku Abubakar ti fesi fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ ti wọn n fi apa janu.

Laipẹ yii ni gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ to tun jẹ ọkan gboogi ni ẹgbẹ osẹlu PDP ni Guusu Naijiria ni ipọ aarẹ sunkan kii ṣe Ariwa ti Atiku ti wa.

Ti Fayose si sọ wi pe ki awọn eniyan maa reti ohun ti oun fẹ ṣe

Bakan naa ni awọn kan n fi apa janu nitori gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa to yan gẹgẹ bi igbakeji rẹ.

Amọ ni oju opo Twitter rẹ, Atiku ni ajumọṣẹ ati iṣọkan ẹgbẹ oṣelu PDP lo jẹ oun ni ogun.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

O ni oun yoo fi iyesi awọn ohun ti awọn eniyan n sọ lai fi ọwọ rọ ẹnikẹni sẹyin.

Iṣọkan wa ninu ile lo jọmi loju, nitori ile la ti n ko ẹṣọ ro ode ti a ba fẹ ki Naijiria ṣe ọkan.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

‘’To fi mọ awọn gomina, aṣofin ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ ti wọn dibo yan ati gbọgbọ awọn ololufẹ mi ati alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn bọwọ fun.’’

Ti wọn ba sọrọ, mo ma n tẹti silẹ, mi o si ki n gbọ nikan, mo ma n ṣiṣẹ lori ohun ti wọn ba fẹ.’’

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3

Atiku fikun un pe ki awọn ẹgbẹ fọkanbalẹ nitori iṣẹ ti bẹrẹ lori ohun ti wọn fẹ.

Ayo Fayoṣe jẹ ojú Atiku, ó ní ‘’Àwa South ló kàn’’
Aworan

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti,Ayo Fayose ti pe fun ki ipo aarẹ orilẹede Naijiria wa si iha Guusu lẹyin ti Atiku Abubakar bori ninu idibo abẹle ni ẹgbẹ oṣelu PDP.

Fayọse lo jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti Atiku Abubakar is wa lati iha ariwa orilẹede Naijiria.

Fayose wa lara awọn oludije fun ipo aarẹ ni idibo abẹlẹ to waye ni ẹgbẹ oṣelu APC.

Ninu atẹjade lori oju opo Twitter ni Fayose ti fi lede pe iha Guusu ni ipo aarẹ tọsi ni saa yii.

‘’ Awa South lo kan’’

O ni iwe ofin ẹgbẹ oṣelu PDP fi aye gba ṣiṣe ayipo ipo aarẹ ni Naijiria labẹ (section 3c) iwe ofin ẹgbẹ.

O ni ẹgbẹ gbọdọ tẹle ofin ati aṣẹ wọn nipa ṣiṣẹ ohun to tọ fun awọn ipo ninu ẹgbẹ oṣelu naa ki ododo le jọba.

‘’Aarẹ to wa lori ipo lọwọlọwọ pa lati iha Ariwa Naijiria, eleyii to fihan pe South lo kan.

O wa fikun un ni ede Yoruba pe ‘’ awa south lo kan’’.

Ọrọ yii ni oludije lẹgbẹ osẹlu APC fun ipo aarẹ Ahmed Bola Tinubu sọ lasiko to n ba awọn alatilẹyin rẹ sọrọ ni ipinlẹ Ogun.

Bakan naa lo fikun pe ki awọn eniyan fi oju sọna si igbesẹ to kan ti oun fẹ gbe.