Ọ̀gá ọlọ́pàá 130 kojú ìgbìmọ̀ olùwádìí lórí ìwà ìbàjẹ́

Ọ̀gá ọlọ́pàá 130 kojú ìgbìmọ̀ olùwádìí lórí ìwà ìbàjẹ́

Nigeria Police

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti kede pe aadoje ọga ọlọpaa yoo fara han niwaju igbimọ to n ri si ọrọ awọn awọn ọlọpaa lori awọn iwa kobakungbe kan niluu Abuja.

Iwadii na to bẹrẹ lọjọ kejidinlọgbọn oṣu yii yoo wa sopin lọla ode yii tii ṣe ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2022.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi lo fi ikede naa ṣọwọ si awọn akọroyin nilu Abuja.

Atẹjade naa ni “Awọn ọga ọlọpaa ti iye wọn jẹ aadoje kaakiri Naijiria yoo fara han niwaju igbimọ oluwadii naa laarin awọn ọjọ yii.”

“Lara awọn ọlọpaa naa ni kọmiṣọna meji, igbakeji kọmiṣọna mẹta, ọlọpaa mẹta ti wọn jẹ Chief Superintendents, Chief Superintendents mọkandinlogun, Deputy Chief Superintendents mejidinlogun ati Assistant Chief Superintendents mẹtadinlaagọrin.”

“Lẹyin ti a ba gbọ ọrọ lati ẹnu wọn, ti a si pari iwadii lori awọn ẹri to wa nilẹ ati ohun to yẹ ni ṣiṣẹ, a oo kan si ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ọlọpaa, Police Service Commission, PSC, fun igbesẹ to kan.”

Adejobi tẹsiwaju pe Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ni oun ni gbagbọ ninu awọn to n dari ikọ oluwadii naa, ati pe igbimọ ọhun yoo ṣe idajọ ododo lori awọn ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan awọn ọga ọlọpaa ọhun.

O fi kun pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣetan lati yọ awọn epo to wa ninu ileeṣẹ naa kuro ki iyi le pada wa fun ileeṣẹ ọhun lawujọ.

O ni “Ọga ọlọpaa tun fi da awọn araalu loju pe ileeṣẹ naa ti ṣetan lati fọ ile rẹ mọ ko le ṣe ojuṣe fun awọn araalu bo ṣew tọ ati bo ṣe yẹ.”