Ǹkan tí ọmọ ọkọ Funke Akindele sọ rèé lẹ́yìn tí ìgbéyàwó rẹ̀ àti JJC Skillz túká

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ọmọ ọkọ Funke Akindele, JJC Skillz, Benito ti sọrọ lori igbeyawo baba rẹ ati Funke to tuka.

Benito sọrọ lẹyin ti baba rẹ kede pe ohun ti pinya pẹlu Funke Akindele.

JJC Skillz ni ohun tiraka lopolopo lati jẹ ki igbeyawo awọn ṣiṣẹ amọ pabo lo jasi.

Amọ Benita to ti sọ saaju pe nkan ko rọgbọ ninu igbeyawo wọn tun jade lati fi ero rẹ han.

Benita ni otitọ ni oun sọ saaju pe igbeyawo baba oun ati iyawo rẹ, Funke Akindele ti fi ori sanpọn.

Bí ìgbèyàwó Funke Akindele ṣe túká rèé...

Ọṣu Kẹrin, ọdun 2022 ni ọmọ ọkọ Funke Akindele, JJC Skillz, Benito wa sori ẹrọ ayelujara lati sọ wi pe nkan ko rọgbọ ninu igbeyawo wọn.

Benito to jẹ ọmọ Mella, obinrin keji to bimọ fun JJC Skills sọ ninu fidio to ṣẹ nigba naa pe nkan ko lọ deede ninu igbeyawo naa.

Benito ni lẹyin ọdun meji ti oun gbe pẹlu wọn, Funke Akindele ki n ṣe ẹni ti eniyan rọ pe o jẹ lawujọ nitori o buru jai.

Amọ JJC ninu idahun rẹ fi atilẹyin han fun iyawo rẹ to si ki ku akinkanju.

Oṣu Karun un ọdun 2022

Amọ ni Oṣu Karun un ọdun yii naa ni iya Benito, Mella sọ loju opo ikansiraẹni Instagram rẹ pe Funke Akindele n dukoko mọ ọmọ oun pẹlu iroyin ikọkọ nipa rẹ, ti ko yẹ ko jade sita.

O fẹsun kan Funke pe o ṣekọlu si ọmọ rẹ, to si ti da ọgbẹ si ni ara ati ni ọkan.

Mella ṣe eleyii lẹyin ti o ti fẹsun kan JJC Skillz naa pe o lu ọmọ oun, to si fẹ paa.

O ni ayederu aye ni wọn n gbe lẹyin ti wọn naa ọmọ oun, ti wọn si da ọgbẹ si ni ara ati ọkan.

Oṣu Kẹfa ọdun 2022

Laarin asiko yii ti ọpọlọpọ iroyin n lọ pe igbeyawo wọn ti daru ni JJC Skillz tun gboriyin dun iyawo rẹ to si ni oun ṣe idaro ile.

Bakan naa ni Funke Akindele gboriyin fun un ni Ayajọ ọjọ awọn Baba ni agbaye to si kii ku itọju awọn ibeji rẹ.

Ọgbọjọ, osu naa ni ọkọ Funke jade sita lati sọ wi pe ko si igbeyawo mọ nitori o ti tuka, ti awn si ti n gbe ni ọtọọtọ lati oṣu mẹta ṣẹyin.

Ọdun 2013 ni igbeyawo Funke Akindele akọkọ tuka.

Ki Funke Akindele to fẹ JJC SkillZ lo ti wa ninu igbeyawo kan tẹlẹ to si ti forisanpọn.

Igbeyawo rẹ pẹlu Kehinde Oloyede forisanpọn laarin ọdun 2012 si 2013.

Ni ọdun 2016 lo pade JJC Skillz ni London ti wọn si ṣe igbeyawo alarinrin.

Obinrin mẹta ọtọọtọ lo si ti bimọ mẹta fun JJC SkillZ,ki Funke to bi ibeji fun.

Ọmọ akọkọ, Tamira jẹ ọmọ ogun ọdun, ikeji Benita kẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun nigba ti ikẹta jẹ ọmọ ọdun mejila.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Ìgbéyàwo Funke Akindele àti ọkọ rẹ̀ ti túká
Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Iroyin to n tẹwa lọwọ bayii ni igbeyawo awọn gbajugbaja oṣerebinrin, Funke Akindele ati ọkọ rẹ, Jjcskills ti tuka.

Ọkọ Funke Akindele lo kede loju ọpọ Instagram rẹ pe awọn mejeeji ko si papọ mọ.

O ni awọn fẹ ki gbogbo eniyan mọ wi pe awọn ko si papọ mọ.

Ọkọ Funke Akindele ni osu mẹta sẹyin ni oun ti ko kuro ninu ile lẹyin ti Funke kan an ni ipa fun oun lati kuro ninu ile.

O fikun un pe oun dupẹ fun ọmọ meji lanti lanti ti awọn jọ ni papọ.

Oko Funke Akindele Bello

Oríṣun àwòrán, @JJCSkillz

Àkọlé àwòrán, Ori Instagram ni Oko Funke Akindele Bello fi ọ̀rọ̀ naa lede si

Ogbeni Bello salaye siwaju pe lati nkan bii odun meji seyin ni igbeyawo yii ti n ni wahala.

Atri pe oun ti sa gbogbo agbara oun lati yanju isoro naa sugbon o ju agbara ori oun lo bayii.

Ati peoun ni lati ko kuro nile leyin ti osere Funke Akindele fi dandna le e lsou meta seyin.

O ni awon kan jo wa si ibi eto ami eye AMVCA ni.

Bakan naa ni Bello to je Baba Ibeji Funke Akindele salaye pe oun se ikede yii fun araye ki won le mọ̀ pe onikaluku ti pin gaari rẹ́.

O ni awon yoo si tesiwaju lati aynju ọ̀rọ̀ awon Ibeji ati pin[pin awon ohun ini ati okowo ti won jọ ni papọ.

Ogbeni Abdul Bello tun ni oun nigbagbo pe gbogbo re yoo yanju si ọ̀na kan tabi ikeji laipẹ̀