Naijiria àti UK tọwọ́ bọ́wé àdéhùn láti máa lé àwọn ọ̀daràn padà sílé
Naijiria àti UK tọwọ́ bọ́wé àdéhùn láti máa lé àwọn ọ̀daràn padà sílé

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Ijọba ilẹ Gẹẹsi ati ijọba Naijiria ti tọwọ bọwe adehun lati maa da awọn ọmọ Naijiria to n wu iwa ọdaran nilẹ naa pada sile.
Akọwe ijọba ilẹ Gẹẹsi, Priti Patel lo kede adehun tuntun naa loju opo Twitter rẹ.
O ni adehun tuntun ọhun waye lẹyin ti wọn tọwọ adehun kan to fara jọ iru eyii ti wọn ni pẹlu Rwanda, bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan ni ko fara mọ adehun ọhun.
Ki ni ohun pato ti ijọba ilẹ Gẹẹsi sọ?
Patel ni “Adehun awa ati Naijiria yoo mu ko rọrun lati le awọn ọdaran kuro lawọn adugbo ati orilẹ-ede wa ki alaafia le jọba nibẹ.”
“Bakan naa ni a oo tun kọju ija si awọn to n gba ọna ẹburu ko awọn atọhunrinwa wọ orilẹ-ede wa.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ohun to yẹ ki o mọ ree
- Ijọba ilẹ Gẹẹsi ti kọkọ tọwọ bọwe adehun kan lati le awọn to fẹ ṣe atipo nilẹ wọn lọ si Rwanda, amọ ile ẹjọ to n ri si ẹtọ ọmọniyan ni Yuroopu ati ile ẹjọ giga kan nilu London bẹgidina aba naa.
- Ninu oṣu Kẹfa ọdun 2022 yii, Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari ṣabẹwo si orilẹ-ede Spain, nibi to ti ṣe ipade pẹlu Aarẹ Pedro Sanchez, to si tọwọ bọwe adehun kan to ni lati ṣe pẹlu bi wọn yoo ṣe maa paarọ awọn ẹlẹwọn, to fi mọ ajọṣepọ nipa ere idaraya, aṣa ati eto ọrọ aje.
- Adehun ti Buhari tọwọ bọ yii n tumọ si pe awọn ọmọ Naijiria to n ṣẹwọn ni Spain yoo lanfaani lati pada si Naijiria lati pari iye ọdun ti ẹwọn wọn ku.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ọmọ Naijiria 38 tí UK dá padà wálé yóò balẹ̀ bàgẹ̀ sí ìlú Eko

Oríṣun àwòrán, Google
O kere tan ọmọ Naijiria mejidinlogoji ti Ilẹ Gẹẹsi da pada si Naijiria yoo pada de loni.
Iya ati iya agba wa ninu awọn ti Ilẹ Gẹẹsi da pada naa, ti wọn yoo si balẹ si ilu Eko.
Bakan naa ni pe ọmọ ilẹ Ghana ti wọn da pada naa yoo wa ninu wọn.
Kilo de ti ilẹ Gẹẹsi fi le wọn wa le?
Ileeṣẹ Ilẹ Gẹẹsi ni Naijiria sọ fun BBC pe awọn ti wọn da pada wale naa jẹbi ẹsun irọ pipa lọna ati lọ si Ilẹ Gẹẹai.
Ọpọlọpọ ninu wọn si ti wa ni ilẹ Gẹẹsi fun ọjọ pipẹ.
Lara awọn wọnyii ni wọn jẹ olufẹ ibalopọ akọ si akọ tabi abo si abo (LGBTQ+) ti wọn salọ si Ilẹ Gẹẹsi lati sa asala fun ẹmi wọn.
Awọn ti wọn le pada wale naa le foju wina ofin
Amọ awọn ajafẹtọ ni igbeṣẹ UK yii le mu ki awọn eniyan naa padanu ẹmi wọn.
Wọn ni awọn obinrin mẹwaa ninu awọn ti wọn da pada lo n koju aisan ọpọlọ ti wọn si n gba itọju lọwọ.
Bakan naa ni awọn miran ninu wọn ni oṣeeṣe ki wọn pa wọn nitori ija ẹsin abi iru ibalọpọ ti wọn faramọ to tako ẹsin tabi ofin ni Naijiria.
Bakan naa ni awọn afẹhọnuhan pejọ ni oṣẹ to kọja lati pe fun ki ijọba dawọ igbeṣẹ pe wọn fẹ dawọ pada wa sile.












