Àjọ NSCDC mú àwọn ọ̀dọ́ tó ń jó ijókíjó ní Gombe 'nítorí ó ń dúnkookò mọ́ ètò ààbò'

Àwọn ọ̀dọ́ ti NSCDC mu

Oríṣun àwòrán, Punch Newspaper

Ajọ alaabo Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC) ti sá fihan ogún ọmọbìnrin ati ọmọkùnrin mẹrinla, fun ẹ̀sùn pe wọn n jo ijo ti ko bojumu.

Oludari àjọ NSCDC nipinlẹ Gombe, Waziri Goni, sọ fun awọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun pe igbeṣẹ awọn afurasí naa dunkooko mọ eto aabo.

O ni ile ijó mẹwaa ni àjọ naa ti ti pa nipinlẹ naa.

O ni yatọ fun ijó ti ko bojumu, ile faaji naa tun jẹ ibi ti àwọn ọdọbinrin ti n ṣe iṣẹ́ aṣẹwo.

"Àwọn kan lara wọn n wa lati awọn ipinlẹ míì, lati ṣe iṣẹ́ aṣẹwo."

Ọgbẹni Goni sọ pe Gidan gala (to tumọ si ile faaji), ni wọn n pe orúkọ ile naa, sugbọn wọn ní ọrẹkunrin.

"Ọjọ́ ori awọn to pọ ju laarin wọn ko tii pe ọmọ ogún ọdún.

" Ile naa ti wa fun ọpọ ọdún katakara si ni àwọn to ni i sọ fun ìjọba pe àwọn fẹ ma a ṣe nibẹ. Sugbọn wọn ti sọ ọ di ile itura ati ibi iṣere."

Oludari àjọ NSCDC ọhun sọ pe díẹ̀ lára àwọn afurasi naa ko lo ju ọ̀sẹ̀ kan ninu igbeyawo wọn, ti wọn fi sa wa si ipinlẹ Gombe fun isẹ aṣẹwo.

O salaye pe pupọ ninu wọn wá lati ipinlẹ Adamawa, Borno, Plateau, Taraba. Àwọn yooku wa lati Kaduna.

O ni igbeṣẹ wọn yoo di ìṣòro fun gbogbo aráàlú, ti awọn ko ba tete mojuto o, nitori pe iru awọn nkan bayii lo n bí ijinigbe, idigunjale ati ẹgbẹ́ okunkun. Ti wọn si tun n fi ọgbọ́n arekereke tàn lára wọn fun pipa.