EFCC mú afurasí ayédèrú 'amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Gómìnà Makinde' fún ẹ̀sùn jìbìtì

Afurasi náà, Olayinka

Oríṣun àwòrán, Effc

Ajọ EFCC, ẹka ti Ibadan, ti gbe arakunrin kan, Babawale Daniel Olayinka, lọ sile ẹjọ́ fun ẹ̀sùn jibiti.

EFCC sọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Wilson Uwajaren fi sita lọjọ Aje pe, ẹ̀sùn jibiti ori ayelujara ni wọn fi kan Olayinka.

O ni kaadi idanimọ ti awọn oṣiṣẹ àjọ naa ka mọ afurasi lọwọ nigba ti wọn mu, fihan pe amugbalẹgbẹ fun Gomina Seyi Makinde, lori eto iroyin, lo jẹ.

Ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun 2022 ni ọwọ tẹ ẹ.

"Oun ati awọn marundinlọgbọn mii ni ọwọ tẹ ni agbegbe Soka, n'ilu Ibadan.

Ẹsun ti wọn fi kan Babawale Olayinka ni pe o ta kaadi ti eeyan le fi gba owo mẹrin lori ayelujara ibanidọrẹ Telegram, , lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 2021.

" Igbesẹ rẹ tako abala karundinlogoji ofin to de iwa ọ̀daràn lori ayelujara."

Bakan naa ni wọn tun fi ẹ̀sùn kan pe o fi parọ lori kaadi idanimọ to fi han àwọn oṣiṣẹ àjọ naa laarin ọjọ́ kọkanla, oṣu Keji si ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022.

Sugbọn afurasi naa sọ pe oun ko jẹbi àwọn ẹ̀sùn ti EFCC fi kan án.

Lẹyin awijare lati ẹnu agbẹjọro rẹ, ile ẹjọ́ gba oniduro rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọ́nà ẹẹdẹgbẹta Naira, ati oniduro meji to gbọdọ ni dukia si agbegbe ile ẹjọ́ naa, to si tun gbọdọ le ko iye owo naa silẹ.

Bakan naa ni Onidajọ Uche Agomoh sọ pe ẹnikan lara awọn oniduro naa gbọdọ kọ́kọ́ fi ẹgbẹrun lọ́nà ọgọrun Naira silẹ lọdọ akọwe ile ẹjọ.

Adajọ tun pàṣẹ pe ko wa ni ọgbà ẹ̀wọ̀n titi yoo fi san mu gbogbo ilana beeli rẹ ṣe.

O si sun igbẹjọ si ọjọ karun-un, oṣu Kẹ̀wá, ọdun 2022.