Adedoyin kọ̀wé sáwọn akọ́ròyìn nílé ẹjọ́ lónìí, ohun tó wà níbẹ̀ rèé

Igbẹjọ lori iku Arakunrin Timothy Adegoke tẹsiwaju loni ni ile ejo giga ipinle Osun to kalẹ silu Osogbo.
Amọ isẹlẹ pabambari kan waye saaju ki igbẹjọ naa to bẹrẹ, eyi ti ko sẹlẹ ri.
Idi ni pe bi awọn afurasi mẹfa ti wọn fi ẹsun kan lori iku oloogbe naa, to fi mọ ẹni to ni ile itura ti alaisi ku si, Ọmọba Rahmon Adedoyin se wọle ẹjọ.
Se ni Rahman Adedoyin bẹrẹ epe ṣíṣe fun ara rẹ ati awọn yoku ti wọn fi ẹsun kan pe wọn dijọ lọwọ ninu iku Timothy Adegoke.
Kia si ni Adedoyin pẹlu awọn afurasi mẹfa yoku sọ iwe kan lu àwọn akọroyin nigbati wọn wọ ninu ile ẹjọ naa eyi to kun fun epe batakun.
Ninu iwe naa ni o ti sọ oko si gbajugbaja agbohunsafẹfẹ kan nilu Ibadan, Oriyomi Hamzat ati awọn agbohunsaffẹ miran to n gbe iroyin nipa rẹ.
Lẹyin ti o ju iwe naa si awọn akoroyin, ni Rahmon Adedoyin bẹrẹ epe ṣíṣẹ fun ara rẹ pe oun ko mo ń kankan nípa ikú arákùnrin Timothy Adegoke,
Bakan naa ni Adedoyin tẹsiwaju lati ṣẹ epe fun awọn to n na ìka si pe o mọ nípa iku arakunrin naa.
Se ni ọpọ eeyan n se haa hin, ọlọpaa ewo ni ti epe, amọ ti ohun gbogbo lọ nirọwọ rọsẹ lẹyin ti igbẹjọ naa bẹrẹ.
Igbẹjọ naa si n tẹsiwaju nile ẹjọ, abọ ohun to waye la mu wa fun yin laipẹ.
















