Ọbẹ̀ Osi, àràmàǹdà ọbẹ̀ tí wọ́n ń fi wákàtí mẹ́rin, tàbí jùbẹ́ẹ̀ lọ sè
Ọbẹ̀ Osi, àràmàǹdà ọbẹ̀ tí wọ́n ń fi wákàtí mẹ́rin, tàbí jùbẹ́ẹ̀ lọ sè
Ọbẹ Osi jẹ gbajugbaja ọbẹ ni aarin awọn eeyan ipinlẹ Kwara.
Ikọ BBC News de ibẹ lati mọ bi wọn ṣe n se ọbẹyii ati iruẹ awọn ounjẹ ti wọn le fi jẹ ti yoo lọ toroo lọna ọfun.
Orukọ miran ti wọn n pe ọbẹ yii ni ọbẹ oro.
Ọbẹ yii jẹ ọbẹ ti eeyan to ba n lo afẹfẹ gaasi yoo ni lati ronu jinlẹ ko to se nitori pe ọbẹ yii n gba to wakati mẹrin lati se e ko to jinna.
Lara awọn nnkan to mu ki ọbẹ yii da yatọ, yatọ si iye akoko to n gba lati se e ni pe wọn ko gbọdọ lo eroja isebẹ igbalode magi sii inu rẹ.
Gẹgẹbi ohun ti wọn ba ikọ wa sọ, ohun miran to ya a sọtọ ni pe ọbẹ osi jẹ ọbẹ ti obinrin to ba ṣẹ̀ṣẹ jade opo ni lati se ranṣẹ si awọn idile ọkọ rẹ ati idile tirẹ gangan lati sọ fun wọn pe oun ti jade opo.



