‘’Ó léwu kí ìjọba gbà kí aráàlú gbé ìbọn, yóò lẹ́yìn’’

Gun Licence: Onímọ̀ kìlò fún Ìjọba lórí àṣẹ kí aráàlú gbé ìbọn torí Nàíjíríà kìí ṣe Amẹ́ríkà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn onimọ nipa eto aabo ni Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba Zamfara to gba awọn araalu ni aaye lati gbe ibọn fun idaabobo wọn.

Eyi ko ṣẹyin aṣẹ tuntun ti ijọba pa pe ki awọn eniyan maa gbe ibọn lasiko lati doola ẹmi wọn lọwọ awọn agbebọn.

Ọsẹ to kọja ni wọn kede ofin tuntun naa nitori bi awọn agbesunmọmi ati agbebọn ṣe n ṣọṣẹ ni asiko yii.

‘’Ti ẹ ba fun awọn eniyan laaye lati gbe ibọn ohun ti yoo ṣẹlẹ, ijọba gbọdọ ṣetan lati koju rẹ.’’

Amọ onimọ nipa eto aabo ni iha Guusu Afrika ni igbesẹ gomina naa yoo da wahala silẹ nitori awọn eniyan ti n kun pe wọn dunkoko mọ wọn nitori ẹya.

O ni awọn Fulani ti n fi ẹhọnu wọn han pe awọn ẹya Hausa n pa wọn lai mọ boya agbebọn ni wọn abi bẹẹkọ.

Bakan naa ni awọn Hausa ni awọn eniyan kan n pa wọn nitori ẹya wọn sunmọ Fulani.

Onimọ nipa eto aabo naa ni awọn eniyan yii n se bẹẹ nitori ero wọn ni pe gbogbo Fulani ni apaniyan, ole ati agbesunmọmi, ti wọn si n jo ohun ini wọn.

O ni ti wọn ba wa fun awọn eniyan laaye lati gbe ibọn ohun ti yoo ṣẹlẹ, ijọba gbọdọ ṣetan lati koju rẹ.

Ibọn kii ṣe gari ti eniyan le ra ni ọja – Akin Adeyi

Onimọ nipa eto aabo ni Naijiria, Akin Adeyi ti ni irunu lo mu ki ijọba ipinlẹ Zamfara kede pe ki awọn araalu maa gbe ibọn.

Adeyi ni o ṣeeṣe ki gomina ọhun sọ bẹẹ lọna ati ki awọn eniyan laya nitori ohun to wa lori ẹfa ju eje lọ.

O ni kii ṣe ọna abayọ̀ ni ki awọn araalu maa gbe ibọn

‘’A o le fi ara wa we Amẹrika lori aṣẹ gbigbe ibọn, a o tii dagba to. Bakan naa ni atunto wa ni Naijiria ko i tii kunjuwọn.

‘’Adugbo to ja geere ko si, ko si ọna ati ibi ti won lọ lati lọ kọ ẹkọ nipa lilo ibọn nitori aṣilo ibọn na yo poju.’’

‘’Nitori Lilo ibọn ko ni atunṣe mọ, ti won ba ti doju rẹ kọ ibi kan.’’

Onimọ naa wa gba awọn eniyan ni imọran wipe ki wọn parapo lati wa wa ọna abayọ si iṣoro ti Naijiria n koju kii ṣe gbigbe ibọn fun awọn eniyan.

A kò láṣẹ láti fún aráàlú ní 'license' láti gbé ìbọn - Ọlọ́pàá Zamfara
Awọn araalu to gbe ibọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Zamfara ti fesi fun ijọba ipinlẹ naa to ni awọn ti fun awọn araalu ni aṣẹ lati gbe ibọn fun idaabobo ara wọn.

Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Zamfara, Ayuba Elkana lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ ni awọn ko ti gba aṣẹ kankan lọwọ ijọba lati fun awọn eniyan ni aṣẹ ki wọn gbe ibọn ilewọ dani.

Elkana ni titi di asiko yii gbendeke wa lori fifun awọn eniyan ni aṣẹ lati gbe ibọn.

O fikun wi pe awọn kii si fun awọn eniyan ni aṣẹ lati gbe ibọn.

Amọ o ni asiko ti awọn agbẹ ma n lọ si oko ni yii, ti wọn si nilo idaabobo amọ awọn ko le ma a tẹle awọn eniyan kaakiri.

''Loot ni awọn agbebọn yii n ṣekọlu si awọn agbẹ, ti a si n sa ipa wa ni gbogbo ọna.

Bakan naa ni a doola ẹmi ọpọ eniyan lọwọ awọn agbebọn naa.

Amọ Atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Zamfara fi sita salaye pe Ijọba ipinlẹ Zamfara ti fun awọn eeyan ni asẹ lati maa lo ibọn atawọn ohun ija oloro miran, ki wọn fi daabo bo ara wọn lọwọ awọn agbebọn atawọn ajinigbe.

Wọn nitori ikọlu to n waye lemọlemọ jẹ ohun to n kọ ijọba atawọn araalu lominu.

Aráàlú, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí gbébọn láti dáàbò bo ara yín – Ìjọba Zamfara
Ibọn lorisirisi

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/Facebook

Ijọba ipinlẹ Zamfara ti fun awọn eeyan ipinlẹ rẹ ni asẹ lati maa lo ibọn atawọn ohun ija oloro miran, ki wọn fi daabo bo ara wọn lọwọ awọn agbebọn atawọn ajinigbe.

Atẹjade kan ti Kọmisana feto iroyin nipinlẹ Zamfara, Ibrahim Magaji Dosara fisita fawọn akọroyin lo sisọ loju ọrọ yii.

Dosara ni ijọba gbe igbesẹ yii nibamu pẹlu bi iwa ipaniyan, ijinigbe ati idunkooko ,ọni se n gbilẹ nipinlẹ naa bayii.

Ijọba ipinlẹ Zamfara si lo kede bẹẹ lẹyin osu diẹ ti ijọba ipinlẹ Katsina naa kede fawọn eeyan ipinlẹ rẹ pe ki wọn maa lo ohun ija oloro fi daabo bo ara wọn lọwọ awọn to ba fẹ kọlu wọn.

Atẹjade naa salaye pe “Iwa ikọlu to n waye lemọlemọ yii jẹ ohun to n kọ ijọba atawọn araalu lominu. Nitori naa, ta ba fẹ koju isoro yii lagbegbe wa,

Ijọba ko ni ohun meji to le se ju pe ko fun awọn araalu ni asẹ lati ni awn ohun ija oloro lọwọ fi daabo bo ara wọn lọwọ idunkooko mọni.”

Dosara ni ijọba ipiblẹ Zamfara ti pasẹ fun kọmisana ọlọpaa nipinlẹ naa lati fun awọn eeyan to yẹ, to si nilo ohun ija lati daabo bo ara wọn ni iwe asẹ lati se bẹẹ.

Ijọba Zamfara wa ni oun gan ni oun yoo lewaju lati mu ko rọrun fun awọn eeyan rẹ lati ni ibọn, paapaa awọn agbẹ, ki wọn le fi daabo bo ara wọn.

“Ijọba si ti pari eto gbogbo lati pin ẹẹdẹgbẹta fọọmu fun agbegbe mọkandinlogun to wa nipinlẹ naa, pe ki wọn pin fun awọn araalu to nilo ohun ija lati fi daabo bo ara wọn, ki wn le fọwọsi awọn fọọmu naa.”

Ipinlẹ Zamfara si wa lara awọn ipinlẹ ti ko si aabo to peye rara lorilẹede Naijiria, tawọn agbebọn ati ajinigbe si maa n yọ wọn lẹnu lojoojumọ.

Koda, ọpọ eeyan ni ko nile lori mọ nipinlẹ naa, ti aimọye ẹgbẹlẹgbẹ si ti di ero ọrun lati ọwọ awọn agbebọn ati ajinigbe.

Àwọn ọmọ onílẹ̀ kọjú ìjà síra wọn l’Ogun, èèyàn kan jáde láyé, àwọn míì farapa
Ogun riot

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Rugudu bẹ silẹ ni adugbo Suncity Estate, to wa ni Mowe, nipinlẹ Ogun lọjọ Ẹti lasiko ti awọn ọmọ onilẹ kan n gbena woju ara wọn.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ṣe ni lawọn janduku naa ṣina ibọn bole fun nnkan bii wakati meji gbako, nibi ti awọn eeyan kan ti farapa, ti ẹnikan si padanu ẹmi rẹ.

Alaga adugbo naa, ọgbẹni Dare Ogunubi ṣalaye fun BBC pe kii ṣe igba akọkọ ree ti wahala yoo bẹ silẹ laarin awọn ọmọ onilẹ ọhun.

O ni awọn ọmọ onilẹ naa ti kọkọ gbe ara wọn lọ sile ẹjọ ṣaaju, ṣugbọn wọn ko ṣiwọ kikọ oju ija si ara wọn.

Ogunubi sọ pe “Ọrọ yẹn ti n ṣelẹ tẹlẹ ti a kan rọra n fọwọ bo mọle ni.”

“A ti ra ilẹ, a ti kọ ile wa, a si ti n gbe ibẹ... amọ o ya wa lẹnu nigba ti a dede ri awọn kan ti wọn ni awọn gan lo yẹ ki awọn ta ilẹ fun wa.”

Bi wahala naa ṣe bẹrẹ

Ogunubi ni aarin awọn ọmọ onilẹ kan ti orukọ wọn n jẹ Taoreed Faronbi ti ọpọ mọ si Baba Alado pẹlu awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ onilẹ mii ti wọn n jẹ Famuwagun, ti ọpọ mọ si Honourable ni rogbodiyan ọhun ti n waye.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọọfisi awọn ẹbi mejeji lo wa ninu adugbo naa, ṣugbọn o jina si ara wọn, amọ ija bẹ silẹ nigba ti awọn ẹbi Famuwagun gbe igbesẹ lati kọ ọọfisi mii si ẹba ọọfisi Baba Alado.

O ni “Ohun ti kan mọ ni pe a kan n gbọ iro ibọn lera-lera fun nnkan bii wakati meji ni.”

Lẹyinorẹyin, awọn kan ṣeṣe, amọ ni nnkan bi aago marun un irọlẹ, ọkan lara awọn janduku naa jade laye.

Ki ni ọlọpaa ṣe?

Ogunubu ṣalaye fun BBC pe inu ibẹrubojo ni awọn eeyan adugbo naa wa bayii, nitori awọn ko mọ ohun to le ṣẹlẹ lẹyin ikọlu ọhun, paapaa ni bayii ti ẹnikan ti padanu ẹmi rẹ.

O ṣalaye pe awọn ti fi ọrọ naa to ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, DPO ati Area Commander Owode Egba leti.

Ẹwẹ, nigba ti akọroyin BBC kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, o ni oun ko gbọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa, amọ oun yoo kan si wa lori iṣẹlẹ naa laipẹ.

Bakan ni a kan si ọga ọlọpaa Area Comander Owode Egba Division ti alaga adugbo naa ni oun fi ọrọ ọhun to leti, Are Comander naa ni ni oun ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa, bẹẹ si ni ẹnikẹn ko kan si oun.