Èmi àti Ropo aya mi kò bá rìn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ lọ Germany, tí ń bá mọ̀ pé wọn yóò mú mi ní Cotonou - Igboho

Sunday Igboho: DSS kò le fi páńpẹ́ mú mi tí mo bá délé, iléẹjọ́ ti dá mi láre

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram

Oloye Sunday Adeyemo Igboho ti sọ pe, laipẹ lai jina, oun yoo pada si Naijiria.

Igboho lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin lorilẹ-ede Benin Replublic.

O ni ko si ohun to jọ pe awọn oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS yoo fi panpẹ ofin mu oun ti oun ba pada wa si Naijiria.

Lasiko to n sọrọ lori bi irinajo naa yoo ṣe jẹ, Igboho sọ pe ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Oyo ti da oun lare.

O ni DSS ko laṣẹ lati mu oun tabi kede pe awọn n wa oun lẹyin idajọ ile ẹjọ naa.

O ni “Mo n pada bọ ni Naijiria laipẹ.”

Ṣaaju ni adajọ Ladiran Akintola ti ile ẹjọ giga naa ti kọkọ sọ pe bi DSS ṣe kọlu ile Igboho lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021 ko ba ofin mu, ti ile ẹjọ ọhun si ni ki DSS san ogun biliọnu naira owo gba mabinu fun iwa ti wọn wu si ati awọn dukia rẹ ti wọn bajẹ.

O ni “Mo ni igbagbọ ninu ẹka eto idajọ.”

Wọn fẹ pa mi, amọ Ọlọrun ko mi yọ

Nigba to n sọrọ nipa ikọlu ti DSS ṣe sile rẹ, o ni DSS atawọn agbofinro to kọlu ile oun loru ọjọ naa fẹ pa oun ni, amọ Ọlọrun lo doola ẹmi oun.

Lori bo ṣe ru ikọla naa la ni pato, Igboho ni akoko ko tii to lati mẹnu le ọrọ naa.

O ni “Ko tii to akoko lati sọrọ, asiko ọrọ ṣi n bọ.”

Mo padanu ẹgbẹlẹgbẹ owo lasiko ikọlu naa

Lori iye owo to padanu lẹyin ti awọn oṣiṣẹ DSS kọlu ile rẹ, Igboho ni ko ṣe fẹnusọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes benz ti iye rẹ to miliọnu marundinlọgọta naira, ọkọ Hilux mẹta ti ọkọọkan rẹ to miliọnu mẹtadinlogun naira, ọkọ G-Wagon ti iye rẹ to miliọnu mejidinlaadọta naira atawọn ọkọ olowo iyebiye mii ni wọn bajẹ nile oun lọjọ naa lọhun.

Nipa bi wọn ṣe fi si atilẹmọle ni Benin Republic, Igboho ni iyawo oun, Ropo, ni wọn kọkọ mu ni papakọ ofurufu Cadjèhoun fun nnkan bii wakati meji gbako, wọn ko si ṣetan lati fi silẹ ayafi ti oun ba yọju.”

O ni “Lẹyin naa ni mo yọju, ti wọn si ko ẹwọn si mi lọwọ ati ẹsẹ, to ba jẹ pe mo mọ ni, n ba ti ma jẹ ki iyawo mi tẹle mi lọ si papakọ ofurufu naa.”

O pari ọrọ rẹ pe awọn mejeji ko ba ti rinrinajo naa lọtọtọ, amọ gbobgo rẹ ye Ọlọrun.