Wo bí arábìnrin yìí ṣé n pèrò sọkọ̀ f'àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú àti ìyè $ tó n ká s'àpò

Aworan Diana
Àkọlé àwòrán, Bi ko ba maa n bawọn oloṣelu ṣiṣẹ, iṣẹ bata tita ni Diana maa n ṣe

Bo se wa ni liki bẹẹ naa lo wa ni gbanja niYoruba a maa wi.

Eyi lo difa fun awọn ọdọ kan ni Kenya ti wọn ri asiko ipolongo ibo gẹgẹ bi anfaani lati pa owo sapo.

Ero wọn yi ko fi taratara yatọ si tawọn ọdọ Naijiria kan to ṣe pe asiko idibo kii ṣe igba ti wọn lero pe awọn oloṣelu le mu iyipada ba igbe aye wọn bi kii ṣe igba ti wọn ri bi asiko lati pawo sapo.

Ọkan ninu awọn ọdọ Kenya ti ọrọ yiba wi ni arabinrin Diana Mwazi.

Ẹni ogun ọdun yi ti di gbajugbaja ninu awọn to n ba oloṣelu pe ero wa sibi ipolongo.

Iṣẹ yi kii ṣe iṣẹ ọfẹ bi kii ṣe pe awọn oloṣelu a maa fun wọn lowo lati pe ero wa si ode wọn.

Ni agbegbe Kibra ni olu ilu Kenya Nairobi lo ti maa n pe awọn ọdọ alainiṣẹ lọwọ pe ki wọn wa darapọ mọ ipolongo awọn oloṣelu.

Bo ba ṣe ri ero pe si ni owo rẹ ṣe n pọ si.

Aworan awọn oloṣelu nibi ipolongo idibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Diana ko yọ ẹgbẹ kankan sọtọ.

Ẹni ba le san owo lo maa n ba pero wa si ipolongo wọn.

O ni''inu mi dun gaan pe asiko ibo ti de bayi.Mo n ri iṣẹ gba daada lọdọ awọn oloṣelu to fẹ kawọn eeyan ri pe ero wa lẹyin awọn''

Ni Kenya bayi, pọpọṣinṣin wa lode nitori idibo ti yoo waye ni ọjọ Kẹsan oṣu Kẹjọ.

Lasiko idibo wọn bi ti Naijiria, niṣe lawọn ẹgbẹ oṣelu maa n lẹ aworan kaakiri ti wọn a si gba ọkọ ti wọn yoo gbe ẹrọ agbounsoke ti orin orisirisi a maa tẹnu wọn jade.

Opurọ ni gbogbo awọn oloṣelu

Ko si oloṣelu kankan to mu ọrọ ero nibi ipolongo ni kekere.

At i awọn to ti pẹ ati awọn to ṣẹṣẹ bẹrẹ alabara daada ni gbogbo wọn jẹ fun Diana.

''Kii ṣe iṣẹ to le ni pe ki eeyan pe awọn eeyan wa sibi ipolongo nitori ọpọ ni ko ṣiṣẹ lọwọ ni Kibra.''

o fi kun pe ''Opurọ si ni gbogbo awọn oloṣelu.Lasiko idibo wọn ma bowa bi eera bo ṣuga ti wọn a si maa ṣe ileri 'Mo ma ṣeyi, maa ṣe tọhun.Mo maa pese iṣẹfun yin'.Amọ bi wọn ba wọle tan wọn ko ni ṣe nkankan.''

O ni oun mu iṣẹ ero pipe wa si ipolongo lafikun iṣẹ bata tita ni.

Lasiko idibo, Diana maa n ba awọn ẹgbẹ orisi ṣiṣẹ ti o si le ba wọn pe to ero bi ogoji si ọgọrun lẹẹkan naa.

''Nkan bi 500 Kenya shillings ($5; £3) ni mo maa n pa nigba mii.Awọn oloṣelu mii a si maa san owo daada.''

O ni lọpọ igba awọn oloṣelu maa n fẹ ki awọn alatako ri pe ero to wa lẹyin awọn pọ tori naa wọn maa n ya aworan ibi ipololongo yi ti wọn a si fi ṣọwọ loju opo ayelujara.

Awọn ero to n pe nkọ, kini ere ti wọn?

Arabinrin Mwazi sọ pe awọn to n wa sibi ipolongo naa maa n ri dede owo ti oun maa n ri gba.

O ni awọn obinrin maa wa daada ṣugbọn o maa n nira lati ko awọn ọdọkunrin wa sibi awọn ipolongo yi.

''Awọn ọkunrin ko ṣe gbọkan le. Lọpọ igba wọn a maa sọ pe owo taa n fun awọn ti kere ju''

O ni nigba miran awọn ọdọ ẹgbẹ alatako a maa ṣe ikọlu si awọn tohun ba n ṣiṣẹ fun.