Ìlú Eko ni ìlú kejì tó ṣòro láti gbé jùlọ lágbàyé – Ìwádìí

Oríṣun àwòrán, @ConnectOnitsha
Ileeṣẹ iroyin The Economist ti gbe iwadii kan jade to fi han pe ilu Eko, ni Naijiria ni ilu keji to ṣoro lati gbe julọ lagbaye.
Eko lo tẹle ilu Damascus, to jẹ olu ilu orilẹ-ede Syria ti ogun abẹlẹ n ba finra lati nnkan bii ọdun melokan ṣeyin.
Ẹwẹ, ilu Vienna, to jẹ olu ilu Austria ti pada soke tente gẹgẹ bi ilu to rọrun lati gbe julọ lagbaye.
The Economist ko fi ilu Kyive, ni Ukraine si ara awọn ilu to yẹwo nitori ogun ti Russia gbe ti orilẹ-ede naa lati oṣu Keji ọdun yii, amọ irawọ Moswo ati St Petersburg ja silẹ nitori awọn gbedeke kan.
Vienna gba ipo kinni lọwọ Auckland, to ja si ipo kẹrinlelọgbọn nitori ajakalẹ arun Coronavirus, gẹgẹ bii Economist Inteligence Unit, EIU, ṣe sọ.
O ni “Vienna to ja si ipo kejila ninu ayẹwo wa lọdun 2021 nitori awọn ile ounjẹ atawọn musiọmu rẹ to di titi pa, ti pada si ipo kinni.”

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilu mẹfa ni Yuroopu lo wa ninu ilu mẹwaa akọkọ
Copenhagen to jẹ olu ilu Denmark lo tẹle olu ilu Austria , ti Zurich, ni Switzerland si n sare tete tẹle awọn mejeji lẹyin.
Ilu Geveva, ni Switzerland lo ṣe ipo kẹfa, Frankfurt ni Germany ṣe ipo keje nigba ti Amsterdam, ni Netherlands ṣe ipo kẹsan an.
Orilẹ-ede Canada naa ko gbẹyin
Calgary wa ni ipo kẹta, bakan naa ni Vancouver ṣe ipo karun un, ti ilu Toronto, ni Canada yi kan naa si ṣe ipo kẹjo.
Ilu Osaka, ni Japan, pẹlu Melbourne, ni Australia ni wọn jọ du ipo kẹwaa.
Paris, ni France wa ni ipo kọkandinlogun.
Awọn ilu ti Eko, ni Naijiria n ba figa-gbaga lapa isalẹ ni Damscus ni Syria, Tripoli ni Libya, Algiers ni Algeria ati Karachi ni Pakistan.















