Ẹ̀yà ara yíyọ ta, ewu àti àwọn tó ń fara kó àásá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni Ọjọbọ ni iroyin gbode pe ọwọ awọn agbofinro nilẹ Gẹẹsi ti tẹ igbakeji aarẹ ile aṣofin agba nigba kan ri lorilẹede Naijiria, Sẹnetọ Ike Ekweremadu ati iyawo rẹ lori ẹsun pe wọn gbe ọmọdekunrin kan wọ orilẹede naa pẹlu erongba ati yọ ẹya ara rẹ lo fun nnkan miran, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni “Organ harvesting”.
Eyi mu ki ọrọ “Ọrgan harvesting” yiyọ ẹya ara eeyan lo fun nkan lọna ti ko tọ o di gbajugbaja ninu ijiroro awọn eeyan lori ayelujara lati igba naa.
Bi eyi ṣe n lọ lọpọ n beere pe ki gan an ni itumọ “Organ Harvesting” tawọn eeyan n pariwo yii?
Ki ni itumọ “Organ Harvesting” gan an ni pato? A o yannana rẹ ninu iroyin yii.
Itumọ “Organ Harvesting”?
Itumọ kan pato ti eeyan lee fun ọrọ yii ni “ki eeyan gba ki wọn pa oun”, eyi ni tita ẹya ara ati lilo ẹya ara eeyan kan fun ẹlomiran.
Eyi ni itumọ ti ajọ ẹtọ ọmọniyan lagbaye gbe kalẹ fun un.
Wọn fi kun un pe ọpọlọpọ orilẹede lagbaye bii China, India ati Sunai Peninsula ni owo yii ti n gbalẹ ju.
Ohun to maa n ṣẹlẹ pẹlu yiyọ ẹya ara lo ni ṣiṣe iṣẹ abẹ lati yọ ẹya ara eeyan lọna ti ko ba ofin mu, fun erongba ati loo fun itọju ẹlomiran.
Ọpọ igba ni igbesẹ yii lee waye tako ifẹ inu ẹni ti wọn fẹ lo ẹya ara rẹ.
Awọn to n fara ko ọṣẹ ẹya ara yiyọ, “Organ Harvesting”

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn eeyan kan wa to jẹ pe funra wọn ni wọn n finufindọ ta ẹya ara wọn fun awọn oniṣowo ẹya ara eeyan ni ọja okunkun lati gba owo, gẹgẹ bi iwe iroyin Delta-net Journal ṣe sọ.
Ọpọ lo ṣi n sọ pe owo nla lo n ba de. Fun apẹrẹ, ẹgbẹrun lọna aadọjọ dọla, ($150, 000) ni owo to kere julọ ti wọn n ta kidinrin.
Lootọ gẹgẹ bi awọn onimọ ṣe sọ, eeyan lee gbe igbe aye rẹ pẹlu kindinrin kan, ṣugbọn kii ṣe gbogbo igba ni eyi maa n ri bẹẹ.
Igba miran si lo maa n jẹ pe tipatipa ni wọn maa fi n yọ ẹya ara ẹlomiran tako ifẹ rẹ.
Awọn miran si wa to jẹ pe nṣe ni wọn maa n fi ọgbọn alumọkọrọyi tan wọn ṣe e.
Ewu wo lo wa ninu tita ẹya ara ẹni?
Ohun to lewu pupọ ni yiyọ ẹya ara ẹni fun ohunkohun.
Lara awọn ewu to si rọ mọ ọ niwọnyii:
- Irora nla
- Ẹjẹ didi
- Arun
- Didaṣẹduro ẹdọ tabi fuku ara eniyan
- Iku












