'Gbogbo èèyàn 43 tó súnmọ́ ẹni tó kó Monkey Pox wọ Kwara láti rí'

Ẹni to ni aarun Monkey Pox

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kọmíṣánnà fún ètò ìlera nípìnlẹ̀ Kwara, Dokita Raji Rasak, ti sọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ nàá, ti fín àwọn òògùn apakòkòrò sí agbègbè tí ààrùn Monkey Pox ti bú jáde.

Dokita Rasak sọ fún BBC pé ní kété tí ìròyìn jáde pé ààrùn nàá wọ agbègbè Gbugbu ní ìjọba ìbílẹ̀ Edu ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

“Gbogbo èèyàn mẹ́tàdínlógún tó ní ìfarakínra pẹ̀lú ọkùnrin awakọ̀ nàá, lá ṣàwárí. Bákan nàá la rí àwọn èèyàn mìí tí àwọn nàá súnmọ́.

“Àpapọ̀ wọn sì jẹ́ mẹ́tàdínlógójì.”

Ẹ̀wẹ̀, Rasak sọ pé ẹnìkan lára àwọn èèyàn nàá ti n fi àpẹẹrẹ Monkey Pox hàn, tí àwọn sì ti n ṣe àyẹ̀wò rẹ̀.

Kéére o! Ààrùn Monkeypox wọ Kwara

Monkeypox

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ṣáájú ni iléeṣẹ́ ètò ìlera ìpínlẹ̀ Kwara ni àwọn ti rí ẹnìkan tó ní ààrùn ‘monkeypox’ ní ìpínlẹ̀ náà.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Kọmíṣọ́nà fétò ìlera ìpínlẹ̀ Kwara, Raji Rasak fi síta lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ní wọ́n ti fìdí èyí múlẹ̀.

Rasak ní láti ìgbà tí wọ́n ti kọ́kọ́ ṣàwárí àrùn náà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nínú oṣù Kejì, ọdún yìí ni àwọn ti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí, tí àwọn sì ti pọn kún ìgbáradì àwọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ní lára awakọ̀ kan, tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, tó ń gbé ní agbègbè Gbugbu ní ìjọba ìbílẹ̀ Edu ni àwọn ti ṣàwárí àrùn náà.

Ó fi kún un pé ọkùnrin náà tó ti wà ní abẹ́ àmójútó àwọn láti ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn nígbà tó bẹ̀rẹ̀ àárẹ̀, tí ara rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣú.

Rasak tẹ̀síwájú wí pé gbogbo àwọn tó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin náà bí i ìyàwó àti àwọn alámùúlétì rẹ̀ tí àwọn náà ń ṣàárẹ̀ ni wọ́n ti wà lábẹ́ àkóso àwọn.

Ó ṣàlàyé pé láti bí ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn ni àwọn ti ni ọkùnrin náà ti wà ní ilé ìwòsàn àwọn nítorí àwọn ti ń fura wí pé monkeypox ló ní.

Bákan náà ló ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n ní àwọn tó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fura sí wí pé wọ́n ní àrùn náà.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ara ìlú lórí àwọn ọ̀nà tí wọ́n le fi dá ààbò bo ara wọ́n lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn yìí.

‘A ti bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera wa kí wọ́n le mọ bí wọ́n yóò ṣe jí gìrì sí ojúṣe wọn àti ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe tí wọ́n bá ṣàwárí rẹ̀ lára ènìyàn’

‘A ti fi tó àwọn iléeṣẹ́ àti lájọlájọ tó yẹ léti pàápàá àjọ NCDC létí.’

Nígbà tó ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọkùnrin náà ti ń gbádùn, ó rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kwara láti máa ṣàmójútó àyíká wọn bó ti yẹ.