Mi ò figbà kankan gbèrò láti ló sáà kan síi lórí ipò, ẹni tó dán an wò rí hmmn... – Ààrẹ Buhari

Ààrẹ Buhari àti Borris Johnson

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti tẹpẹlẹ mọ ìfarajìn rẹ̀ láti gbé ìjọba kalẹ̀ ní kété tí sáà bá ti pári ní ọdún tó ń bọ̀.

Buhari ní òun ní ọ̀wọ̀ tó ga fún ìwé òfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà èyí tó làá kalẹ̀ wí pé sáà méjì ni Ààrẹ tàbí ẹnikẹ́ni tí wan bá dìbò yàn ní Nàìjíríà le lò.

Bákan ló ní àwọn tó gbèrò láti yí òfin padà ní ọjọ́ kìíní àná, tí wọ́n gbèrò láti lo sáà mẹ́ta nípò, àbùkù ni wọ́n bá bọ̀ níbẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ààrẹ Muhammadu kò dárúkọ kàn ní pàtó, ìgbágbọ́ wà pé Ààrẹ àná, Olusegun Obasanjo tó ṣe ìjọba láàárín ọdún 1999 sí 2007 tó tún gbèrò láti lo sáà kan si ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ń bá wí.

Èyí ni èsì Ààrẹ Muhammadu Buhari lórí ìbéèrè wí pé ṣe yóò tún díje ní ẹ̀ẹ̀kan sí tí ààyè bá gbàá láti tún tukọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Níbi ìpàdé tí Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe pẹ̀lú alákòso orílẹ̀ èdè Gẹ́ẹ̀sì, Borris Johnson níbi ìpàdé àwọn olórí orílẹ̀ èdè àjọ Commomwealth tó wáyé ní Kigali, orílẹ̀ èdè Rwanda.

Àtẹ̀jáde látọwọ́ agbẹnusọ Ààrẹ Buhari, Femi Adesina ní Ààrẹ àti Johnson tún jíròrò lórí ọ̀rọ̀ Nnamdi Kanu tó ń pè fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra tó wà ní àhámọ́.

Ààrẹ ní àwọn kò dènà agbẹjọ́rò Kanu láti máa yọjú nítorí gbogbo àǹfàní ní àwọn ń fún láti wí tẹnu rẹ̀ lórí gbogbo ẹ̀sùn tó fi ń kan ìjóba Nàìjíríà nígbà tó wà ní ilẹ̀ òkèrè.

Ó fi kun wí pé àwọn kò ṣetán láti gba ìdáǹdè rẹ̀ nítorí nígbà tí wọ́n fún ní ìdáǹdà láàkọ́kọ́, níṣe ló na pápá bora.

Nìgbà tó ń fèsì sí ọ̀rọ̀ Johnson lórí ìpinu ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì láti ran Nàìjíríà lọ́wọ́ lẹ́ka ètò ààbò, Buhari ní gbogbo ipá ni àwọn ti ń sà láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ènìyàn wí pé ọ̀dájú ènìyàn ni yóò kàn máa pa ẹ̀dá ẹgbẹ́ rẹ̀.

Ó ní àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń so èso rere àti pé àwọn ènìyàn ti ń mọ̀ pé àwọn tó wà nídìí Boko Haram kò jà fún ẹ̀sìn kankan bíkòsẹ wí pé ẹni ibi pọ́ńbelé ni wọ́n.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Borris Johnson ní inú òun dùn sí gbogbo okoòwò tó ń wáyé láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì àti wí pé àwọn tún ti ṣetán láti mú àdínkù bá owó orí àwọn ọjà kan tó ń wá sí Nàìjíríà láti ọ̀hún.

Johnson ní òun fẹ́ mọ̀ bóyá gbogbo ohun tí àwọn ń ṣe dára tó àti láti wá ọ̀nà tí yóò tún fi dára si.