Báyìí ni àwọn agbébọn ṣe bẹ́ orí gbajúgbajà oníṣòwò ní Anambra

Nelson Achukwu

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn agbébọn ti bẹ́ gbajúgbajà oníṣòwò ní ìpínlẹ̀ Anambra, Nelson Achukwu lórí.

Achukwu ló ti fìgbà kan rí jẹ́ aṣòfin láti ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Nnewi.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní bí oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ni àwọn agbébọn ti kọ́kọ́ jí Achukwu gbé fẹ́sùn wí pé ó ń tú àṣírí àwọn fún iléeṣẹ́ ológun.

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó lò ní àhámọ́ àwọn ajínigbé náà ni wọ́n tu u sílẹ̀.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Ikenga Tochukwu ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ni àwọn agbébọn tún lọ ká Achukwu mọ́lé rẹ̀ tó wà ní Mkpor ní nǹkan bí aago mẹ́wàá kọjá ìṣẹ̀jú mẹ́ẹ̀dógún.

Tochukwu ní ààlà Uke àti Ukpor ni àwọn ti rí òkú Achukwu.

Ó ní ìwádìí àwọn ń tẹ̀síwájú láti fojú àwọn aṣebi tó ṣekúpa Achukwu hàn tí wọ́n yóò sì fojú winá òfin.

Ètò ààbò ní ìpínlẹ̀ Anambra ti ń kọ àwọn ènìyàn pàápàá bí ìpànìyàn àwọn tó lórukọ ṣe ti ń wáyé léraléra ní ìpínlẹ̀ Anambra.

Nínú oṣù Karùn-ún, ọdún 2022 ni àwọn agbébọn ṣekúpa ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Anambra, Okechukwu Okoye lẹ́yìn tí wọ́n ji gbé.

Òun àti àwọn abẹ́ṣinkáwọ́ rẹ̀ kan, Cyril Chiegboka ni wọ́n pa.

Nelson Achukwu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ta ni Nelson Achukwu?

Nelson Emeka Achukwu jẹ́ ọmọ bíbí Ukpor ní ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Nnewi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Ogbatulenyi.

Agbẹjọ́rò àti olóṣèlú ni pẹ̀lú.

Ní ọdún 2003 ló jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ìpínlẹ̀ Anambra.