Lẹ́yìn tó dárapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, igbákejì Gómìnà Oyo bẹ̀rẹ̀ isẹ́ l'ọ́fíìsì tuntun

Gomina Seyi Makinde pẹlu Igbakeji rẹ Rauf Ọlaniyan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/twitter

Igbakeji Gomina Ipinlẹ Oyo, Onimọẹro Rauf Olaniyan ni o pada ṣe lenu isẹ rẹ loni lẹyin ti o kede pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP lọ si ninu ẹgbẹ oselu APC.

Olaniyan ni Gomina Seyi Makinde gbe ọfisi rẹ kuro ninu ọfisi ìjọba ti o si gbe lo si ika ijọba naa ton ri si ayika ati ohun alumọni ni Ipinlẹ naa

Igbakeji Gomina naa ti wa bosi ọfisi rẹ tuntun naa lati tẹsiwaju ninu isẹ rẹ gẹgẹ bii igbakeji Gomina Ipinlẹ Oyo.

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ Rauf Ọlaniyan ni ọfiisi tuntun ti wọn fi si

Lai pẹ ni Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo fi ẹsun marun un ọtọtọ kan igbakeji gomina ipinlẹ naa, ti Mẹrinlelogun ninu awọn aṣofin ile naa lo tọwọ bọwe ẹsun naa, eyii ti wọn ka ni gbagede ile niluu ibadan.

Gẹgẹ bii ohun to wa ninu iwe naa, lara ẹsun ti wọn fi kan Olaniyan ni aṣilo ọọfisi, iwa kobakungbe, ṣiṣi owo ilu na, aibọwọ fun awọn alaṣẹ, atawọn ẹsun mii.