Ìjọba àpapọ̀ tún wọ́ Sunday Igboho padà sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nilùú Ibadan

Aworan ile ẹjọ naa ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday igboho

Ọpọ awọn ololufẹ gbajumọ ajafun idasilẹ orilẹede Yoruba ni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho lo kun ilee ẹjọ kotẹmilọrun to wa nilu Ibadan l’Ọjọru.

Ni ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa nilu Ibadan ni igbẹjọ ti n waye lori ẹjọ kotẹmilọrun ti ijọba apapọ pe tako Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ eeyan mọ si "Sunday Igboho".

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, Sunday Igboho wọ ijọba apapọ orilẹede Naijiria lọ si ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ niluu Ibadan, nibi ti o ti beere fun ẹẹdẹgbẹta Biliọnu naira, owo gba mabinu fun ile rẹ ti ileeṣẹ ọtẹlumuyẹ orilẹede Naijiria, DSS kọlu lọjọ kini oṣu keje ọdun 2021.

Ile ẹjọ naa gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ ọun nigba naa pe ki ajọ agbofinro DSS o lọ san ogun biliọnu naira fun Sunday Igboho.

Ijọba apapọ ko tẹwọgba idajọ ile ẹjọ to ni ki wọn san ogun Biliọnu naira fun Sunday Igboho, eyii lo si ṣokunfa bi ẹjọ naa ṣe de ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Awọn ero niwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Ibadan

Aago meji ọsan Ọjọru ni igbẹjọ naa bẹrẹ, ṣugbọn awọn alatilẹyin Sunday ti o fara han nile ẹjọ ko ni anfani lati wọle sinu gbọngan igbẹjọ ni ile ẹjọ naa.

Awọn agbofinro to duro lẹnu ọna ṣe alaye wi pe eeyan perete nikan ni yoo lanfani lati de ibi igbẹjọ naa.

Bakan naa ni awọn akọroyin ko ni anfani lati wọle si ibi igbẹjọ naa.

Agbejọro fun Sunday Igboho, Amofin Yọmi Aliyu wa nibi igbẹjọ naa ti o n lọ lọwọ bayii.