Ìdí tí èmi Pásítọ̀ ṣe ń bu owó tabua fáwọn ọ̀dọ́ ní Ṣọ́ọ̀ṣì mi, tí mo tún ń bá olórin Davido, Portable Zazzu ṣe rèé

Àkọlé fídíò, Pastor Tobi Adegboyega: Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ gaan ni mo fẹ́ bá rìn, ẹ̀yin Pásítọ̀ akẹ́gbẹ́ mi olód

Ẹnu bẹrẹ si ni kun yumu-yumu lori Pasitọ Tobi Adegboyega ti ijọ Salvation Proclaimer Ministry to wa ni ilu London lẹyin ti iroyin gba ori ayelujara kan pe ijọba ilẹ UK fẹ ti Ṣọọṣi rẹ pa.

Bakan naa ni iroyin tun jade sita pe o ni awọn owo gọbọi gọbọi kan ti oun ati ijọ rẹ ko lee ṣalaye ibi to ti wa ati bi wọn ṣe na a.

Pasitọ Tobi Adegboyega
Pasitọ Tobi Adegboyega

Iwadii fi han wipe bujẹ-bu-danu ni Pasitọ ẹni to ṣẹ le ni Ogoji ọdun yii torii bi o ṣe maa n bu owo na fun awọn ọmọ ijọ rẹ ti ọpọlọpọ wọn jẹ ọdọ ati awọn ọdọ miiran lorilẹede Naijiria ati to ti ran lọwọ kaakiri agbaye.

Eyi lo mu ki awọn eeyan maa bere ibeere lootọ pe wa, nibo ni aduru owo ti Pasitọ yii n na ti n ya wa ti kii gbẹ to bẹẹ ti ijọba UK fẹ gbe Ṣọọṣi rẹ ti pa?

Idahun Pasitọ Tobi Adegboyega

Pasitọ Tobi Adegboyega

Olusọ ijọ SPAC Nation ni lati ọdun 2005 ti oun ti kuro ni Naijiria lọ si London lati lọ ka nipa imọ ofin ṣugbọn ti eyi yipada oun rii pe gbogbo ọdọ ti oun ba nibẹ yẹn nilo ẹni to lee fun wọn ni iran ko si tọ wọn sọna.

"Mo rii pe bi awọn ọdọ to n dagba si ilu Lonodn ti awọn obi wọn ṣi kuro ni

Naijiria ṣe n gbe igbe aye wọn ko dara to ati pe awọn ara London n ṣe wọn bii ẹni ti ko lẹtọ daadaa nilu, ojojumọ ni wọn yin eeyan nibọn ni adugbo wa nigba naa... Wọn o jẹ ki wọn gberi, wọn o jẹ ki wọn lo aluyọ".

Pasitọ Tobi Adegboyega

"Ẹlẹṣẹ gangan ni mo fẹ maa ba rin"

Pasitọ Tobi ni awọn Pasitọ mii ti wọn ro pe oun n da ẹṣẹ nipa biba awọn olorin aye rẹ ti wọn n wa si ijọ rẹ ti oun naa n lọ si ile orin wọn ti wọn ba ti lọ si UK, nkan ti oun fẹ maa ṣe gangan niyẹn.

"Ẹlẹṣẹ gangan lemi fẹ ba rin, awọn to ba ti gba pe awọn di olododo ki wọn ma ba mi ṣe tori nkan ti Kristi fẹ ni mo n ṣe".

Ijọ Pasitọ Tobi

Lori Ibasepọ Pasitọ Tobi pẹlu Davido, Zazzu ati bẹẹ bẹẹ lọ

"Mo lọ si "show Davido lootọ, koda to ba n ṣe ikomọ to ni ki n wa, maa lọsibẹ.

Ti kii ba ṣe ti awọn Davido atawọn to ku ta n sọ yii, ọpọ lọpọ ọmọ Naijiria ni a di alainiṣẹ".

Nkan to ni o pa oun ati Davido pọ ni pe awọn ni ọkan kan to n ṣe nkan to dara fun awọn eniyan.