Ọ̀ràn wo ni 'Portable' dá tí Ọlọ́pàá ní kó fi ara rẹ̀ rán sí àgọ́ wón?

aworan onkorin Portable

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gbajugbaja olorin Habeeb Okikiọla, ti ọpọ mọ si Portable to kọ orin ZaZu Zeh" ni Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede pe ko fẹsẹ ara ẹ rin wa si agọ wọn to wa ni agbegbe Eleweẹran niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, lẹyin ti wọn fi ẹsun iwa ọdaran kan an latari bi oun pẹlu awọn kan ṣe ṣe ikọlu si arakunrin kan,

Ileeṣẹ olopaa naa wa ni ti o ba ko ti ko yọju, yoo ri pinpọn oju ijọba ni.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ti o jẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ninu atẹjade kan to fi sita fun awọn akoroyin ni ana ode yi ṣafihan irufẹ iwa ti Portable hu ni agbegbe kan ni ipinlẹ Ogun gẹgẹ bi iwa ti ko ba ofin mu, ti o si jẹ idi tawọn fi n wa olorin naa.

Ninu fidio to bo si ori ayelujara, o fihan pe Portable paṣẹ fawọn ọmọ ita kan pe ki wọn ba oun fiya jẹ ọmọkunrin kan to ṣẹ apejuwe pe o ṣẹ oun, ti awọn ọmọ ita naa si bẹrẹ lilu arakunrin naa pẹlu ifoti, ifonu.

Oyeyẹmi ni iyalẹnu ni o jẹ pe nitori irufẹ iwa naa ni ko yẹ ko ti ọwọ gbajugbaja olorin naa jade lati bi o ṣe jẹ awokoṣe fun awọn ọdọ ati awọn ọmọde.

O ni irufe iwa naa ko ri aye ninu ipinlẹ Ogun, ti o si jẹ idi ti awọn fi ṣe iwadi lori fidio naa, ki awọn si le fidi ododo mulẹ.

Atesita naa wipe;

“A n lo anfaani yii, lati gba Okikiọla Habeeb, ti inagijẹ rẹ n jẹ Portable lamọran pe ko ṣafihan ara ẹ ni teesan ọlọpaa to ba sun mọ ọn ju lọ ni ipinlẹ Ogun, tabi ko wa si olu-ileeṣẹ wa l’Abẹokuta".

aworan okorin Portable

Oríṣun àwòrán, Screenshot

"To ba kuna lati ṣe bẹẹ laipẹ, a maa kede pe kawọn agbofinro mu un nibikibi to ba wa, gẹgẹ bii afurasi ọdaran."

"Iru iwa ṣiṣedajọ lọwọ ara ẹni bii eyi taa ri ninu fidio yii ki i ṣe iwa to yẹ lawujọ, ko si ba iwa ọmọluabi kankan mu, o tako ofin ilẹ wa patapata. O jẹ aṣa to le fẹsẹ awọn ọdọ mi-in le ọna iwa abeṣe lawujọ."

Wọn fi kun un wipe ofin o mọ ipo tabi aaye tẹnikẹni le wa, "ẹni ba fọwọ pa ida ofin loju, ofin yoo pa iru wọn lọwọ gbẹrẹgẹdẹ bii abẹfẹlẹ ni.”