'Ẹ gba owó lọ́wọ́ olóṣèlú tó bá fẹ́ ra ìbò ní 2023, àmọ́ ẹ dìbò fún ẹni tó kójú òsùnwọ̀n'

Awọn onimọ nipa eto osẹlu Naijiria, ti bẹrẹ si ni fi ifoya han lori pe o ṣeeṣe ki awọn oludije kan fi owo ra ibo lọdun 2023, ti wọn si le jawe olubori botilẹ jẹ pe wọn o koju osunwọn.
Ifoya yii n waye nitori fidio kan to jade lasiko eto idibo gomina to waye nipinlẹ Ekiti, eyi to ṣafihan bi awọn oloṣelu kan ṣe pin owo fun awọn oludibo.
Ẹni to jẹ alaga fun ibudo to wa fun idagbasoke ijọba awaarawa, Center for Development and Democracy, nilu Abuja, to si tun jẹ onimọ nipa eto oṣelu, Ọmọwe Kole Shettima, sọ fun BBC pe nkan ti awọn oloṣelu naa ṣe lewu pupọ.
O ni “to ba jẹ pe bi nkan sẹ ri niyii, a jẹ pe oludije to ba lowo lọwọ ni yoo jawe olubori ninu idibo to n bọ, bi ko ba tiẹ kun osunwọn:.
Ọmọwe Shettima sọ pe airo naa to n ba ọpọ finra ni Naijiria, le mu ki awọn oloṣelu lo anfaani naa lati fun awọn eeyan lowo ki wọn o le dibo fun wọn.
“Ṣugbọn imọran mi fun awọn oludibo ni pe, ki wọn o gba owo lọwọ ẹnikẹni to ba fun wọn lowo nitori ki wọn o le dibo fun, amọ ki wọn o dibo fun ẹnikẹni ti wọn ba lero pe ipo naa tọ si.”
Ẹlomiran to jẹ ọmọ ẹgbẹ to n ja fun ijọba awaarawa nipinlẹ Kano, Amofin Aisha Ali Tijjani, naa sọ fun BBC pe awọn obinrin ni awọn oloṣelu to n ra ibo ṣaba ma n dojukọ, lati fun ni owo ati awọn nkan miran bi ọṣẹ.
O ni awọn obinrin n gba awọn nkan na nitori pe wọn ko mọ ẹtọ ati ominira ti wọn n sọnu nipa tita ibo wọn.
Amofin Aisah Tijjani sọ pe awọn obinrin gbọdọ mọ pe anfaani ọlọjọ diẹ, ni nkan ti oloṣelu ba fun wọn lasiko idibo.
“Ijamba ni wọn n ṣe fun ara wọn ti wọn ko ba yan adari to tọ̀.”
Amofin naa sọ pe gbigba owo lọwọ oloṣelu lasiko idibo, dabi igba ti eeyan ba ta ẹ̀tọ́ rẹ fun ọdun mẹrin, tabi to n kanju la ọbẹ gbigbona.
Fifi owo ra ibo, ti awọn eeyan kan tun ma n pe ni dibo ko o sẹbẹ, ko ṣẹṣẹ bẹrẹ ni orilẹ-ede Naijiria.
Ko si fẹ ẹ si asiko idibo boya ni ijọba ibilẹ, ipinlẹ tabi gbogboogbo, ti awọn eeyan kii fi ẹsun kan awọn oloṣelu pe wọn n fi owo ra ibo.
Eyi si ni ọpọ gbagbọ pe o mu ki awọn oloṣelu ti ko koju osunwọn ma a di adari ni Naijiria, to si tun n sọ wọn di ẹni to n ko owo ilu jẹ.












