Àwọn alárùn ọpọlọ tí gba ètò ìjọba Orílẹ̀èdè Nàìjíríà kan - Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Screemshot
Oludije fun ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ti pariwo sita pe awọn alaarun ọpọlọ lo n ṣe ijọba orilede Naijiria, ti wọn sin ṣe akoba fun eto ijọba.
O sapejuwe ida aadọrin ninu oloṣelu gẹgẹ bi alaarun ọpọlọ ti ko yẹ ki wọn di eto ijọba orilede Naijiria mu.
Obi lo sọrọ yi sita lọjọ aiku niluu Abuja nigba ti o darapo mọ ijọ Revival House of International Church (RHOGIC).
O ni alarun ọpọlọ ni yoo gbe owo to to bilionu marundinlaadọrun naira to wa fun ara ilu si apo ara rẹ.
O tẹsiwaju pẹ opo lara awọn oloselu Naijiria ni ko yẹ ko wa ninu eto ise ijọba nitori alaarun ọpọlọ ni wọn.
O kilọ pe ti awọn oloselu naa ba si wa ninu eto iṣejọba orilede Naijiria, ko ni si ilọsiwaju ati pe ọpọ ọmọ orilede yii ni a maa jẹ iya.
“ A ko gbọdọ fi aye gba awọn ọmọ ita lati tẹsiwaju ninu isakoso orilede Naijiria, ọmọ Naijiria, ẹ jẹ ka gba orilede wa pada lọwọ awọn alarun ọpọlọ”
“ ida adọrin ninu awọn to n se ijọba le wa lori ni ko yẹ ko wa ni bẹ sugbọn mo ti ni orilede Naijiria ni a ti ma fi aye gba alarun ọpọlọ lati se ijọba le wa lori.”
“ Orilẹede Naijiria nibi ti ipadasẹyin ti n sẹ ijọba.”
“Ti a ba ri awọn ọdọ ti wọn sẹtan lati gba ijọba, nnkan yoo pada dara fun wa.”
Bakan naa, akowe fun ẹgbẹ oselu Young Peoples Party, Vidiyano Bamaiyi ni ọpọ oloselu orilede Naijiria ni le pe ni awọn agbesunami oloselu.
O ni awọn agbesunmọmi oloselu ti gba isakoso orilede Naijiria, ti wọn o ni anfani ti wọn fẹ se fun ilọsiwaju orilede.















