Wọ́n gba Mílíọ̀nù kan, Sígà tó pọ̀, Ọ̀tí Oríjín àti ìrẹsì kí wọ́n tó tú Olùṣọ́ Celestial Ewekoro sílẹ̀

Fulani Bòròró ni àwọn tó jí wa gbé, ìran Yorùbá ẹ fura, 'Network'ni wọ́n

Se ẹ ranti Olusọ ijọ Celestial Church of Christ to wa ni Ewekoro ti wọn ji gbe laipẹ?

BBC Yoruba ti fidiẹ mulẹ pe wọn ti tu wọn silẹ lọsan yii.

Olusoagutan ile ijosin Celstial naa, Oluwatomisin Ehuwaojomo to fi idi isẹlẹ naa mulẹ ṣalaye fun BBC Yoruba pe wọn ti ko awọn mejeeji ti wọn tu silẹ naa lọ sile iwosan fun itọju to peye.

Aworan awọn ajinigbe agbebon

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Olusoagutan ile ijosin Celstial naa, Oluwatomisin Ehuwaojomo sọ fun BBC Yoruba pe ijọ naa san milionu kan naira, ọpọlọpọ siga, #oti lile Orijin ati Irẹsi.

O ni pe ikilọ wa fun iran Yoruba bayii nitori pe, gbogbo nkan to ṣẹlẹ naa fihan pe ọwọ ti kan ọwọ lori rẹ̀

O ni pe awọn Fulani Bororo lo ji Oluso ijọ Celestial naa ati oluko ile ẹkọ ọjọ isinmi naa gbe lasiko ti iṣọ oru n lọ lọwọ nile ijọsin naa ni Ewekoro

Bakan naa lo tun sọ pe wọn na awọn mejeeji na a to si fi apa diẹ si wọn lara.

Olusọ ni pe gbogbo igbo ilẹ Yoruba ni awọn boroor yii mọ patapata ati pe wọn aytọ si awọn Fulani to n da ẹran.

Ẹni mẹ́rin ni agbébọn kọ́kọ́ mú nínú ìṣọ́ òru náà kí àwọn mẹ́jì tó móríbọ́

Àwọn ajínigbé ti dín owó tí wọ́n n bèèrè kù sí #10mílíọ̀nù báyìí

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awon omo ijosin meji kan ni Celestial Church of Christ to wa ni Wasinmi, nijoba ibile Ewekoro nipinle Ogun ti awon agbebon jigbe lọ́jọ́ ajé ose yii lasiko iso òru ijo naa ni won ti berre fun miliọnu mewaa ki won to daa wọn silẹ.

Olusoagutan ile ijosin Celstial naa, Oluwatomisin Ehuwaojomo to fi idi isẹlẹ naa mulẹ, ṣalaye pe awọn mẹrin ni awon agbebon naa koko mu ti awon meji jaja bo ti won si gbe meji lo.

Olusoagutan Oluwatomisin salaye pe àádọ́ta millionu ni awon agbebon beere fun ki won to din ku si millionu mewaa.

Eeyan mẹji ni awọn ajinigbe agbegbon ji gbe ni ile ijọsin Celestial Church of Christ ni agbegbe Wasimi to wa ijọba ibilẹ Ewekoro ni ipinlẹ Ogun lọjọ Iṣẹgun.

Amugbalẹgbẹẹ Olusọ ati Olukọ Sunday School ni awọn ajinigbe gbe lo, ti wọn si ti n beere fun aadọta millọnu naira ki wọn to tun wọn silẹ.

Oṣojumikoro kan to wa nibi iṣẹlẹ naa ni bi ago mejila ku iṣẹju diẹ ni awọn agbegbọn ti won wọ asọ soju ya wọle si ile ijosin naa pẹlu ibọn ati ada.

Ó tún ti ń rúgbó bọ̀! Àwọn Agbébọn jí Olùsọ́ àti Olùkọ́ 'Sunday School' gbé lásìkò ìṣọ́ òrú ní Ewékorò, bèèrè #50m

Oluwajese Sunmade to ba awọn akọroyin sọrọ ni awọn agbegbọn naa ni wọn gbe ibon ati ada dani, ti won si bere lọwọ awọn olujọsin pẹ nibo olusọ agba wa.

“Wọn bẹrẹ lowo mi pẹ nibo Olusọ agba wa, mi o da wọn lohun.’’

“ Wọn ni awọn ma fun mi ni ibon sugbọn mo ri aye lati salo.”

“Ariwo naa lo ji amugbalegbe Olusọ ati Oluko Sunday School, ti wọn si gbe awọn mejeeji lọ.”

Àwòrán oluso ati oluko

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oludasile ilejọsin naa, Woli Oluwatomisin Olugbebi ni ko to iṣẹju mẹwaa ti oun kuro ni ile ijọsin ni awón agbebọn naa se ikọlu si ile ijọsin ọhun.

O ni awọn agbebọn naa ti pẹ si ori ẹrọ ibanisọrọ oun, ti wọn n si bere fun aadota milonu naira

“Lẹyin wakati mẹji ti iṣẹle na sẹlẹ ni amugbalegbe mi pẹ mi pẹ awọn agbebọn beere fun aadota milonu, mo ni emi ko ni owo naa nitori mi o gba owo osu.”

Àwòrán ileese olopaa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Agbenuso fun ileese olopaa, Abimbola Oyeyemi fi di iṣẹlẹ naa mulẹ, ti o si ni iwadi di bẹrẹ lati fi ofin mu awọn ajinigbe naa ati lati doola awọn to wa ni ahamo awọn ajinigbe naa.

O ni ileese olopaa ipinlẹ Ogun ti bere iwadi lati ri pe owọ te awọn ajinigbe naa.