Ẹ̀hun ọ̀rọ̀ ni, kò sí ẹrí tó fíhàn pé ISWAP ló ṣé ikọlù sí ilé ìjósìn Owo -Fayemi

Oríṣun àwòrán, Facebook/JKayodeFayemi
Gomina ipinlẹ Ekiti Kayode Fayemi ti sọrọ tako ọrọ ti ijọba Naijiria fi lede pe ikọ agbesunmọmi ISWAP lo wa nidi ikọlu ile ijọsin ilu Owo.
Lasiko to n kopa lori eto ileeṣẹ amohunmaworan Naijiria Channels TV kan lo ni ko si ẹri kankan to tka si ero pe iṣẹ ọwọ ISWAP ni ikọlu yi.
Fayemi to tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn Gominha Naijiria ni kawọn eeyan jẹ kawọn agbofinro pari iwadii tan ki wọn to bẹrẹ si ni s ẹni to ṣe ikọlu naa.
O ni nkan ibanujẹ ni ipo ti eto aabo wa ni orileede Naijiria ni paapa ni ila oorun Guusu Naijiria.
Fayemi lawọn Gomina ilẹ Yoruba ti n ṣapa lati kọdi iru iṣẹlẹ ikọlu yi to pada waye nipa idasilẹ ikọ alaabo Amọtẹkun.
O ni o ṣe pataki lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro lati ṣe atunṣe eto aabo ilẹ Yoruba.
''Owo ni gbogbo wa ti wa bayi. Ikọlu ti wọn ṣe si Owo yi gbogbo wa ni ikọlu naa ba''

Oríṣun àwòrán, Facebook/JKayodeFayemi
Ṣe lootọ ni pe ISWAP lo wa nidi ikọlu naa?
Esi ti Fayemi fọ nigba tawọn atọkun eto beere pe ṣe o ro pe awọn ikọ agbesunmọmi ISWAP lo wa nidi ikọlu yi ni pe oun ko ro bẹ.
Alaga ẹgbẹ awọn Gomina naa si sọ pe ẹhun ọrọ ti ko fẹsẹ mulẹ lọri yi jẹ si oun.
''Lọkan mi, gbogbo ọrọ nipa ISWAP,Boko Haram tabi awọn kraan, ọrọ ahesọ ti ko fẹsẹ mulẹ lawọn ọrọ yi jẹ nibi ti ọrọ de duro yi.''
''Mi o ti ri ẹri kankan to fẹsẹmulẹ to si fihan pe awọn ikọ wọnyi lo wa nidi ikọlu yi''















