Àrokò ibi àti ẹ̀rù fún Akeredolu pẹ̀lú Yorùbá ni agbébọn fi ìkọlù Ọwọ ṣe – Soyinka

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ọjọgbon ati Onkọwe, Wọle Soyinka ti ṣapejuwe ikọlu to waye ni ilu Ọwọ gẹgẹ bi aroko iṣẹ ibi si gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ati gbogbo awọn ọmọ Yoruba.
Soyinka sọ eleyii lasiko to n ṣabẹwo ibanikẹdun si gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu.
O ni ikọlu si Ile Ijọsin St. Francis Catholic Church, Ọwọ,nipinlẹ Ondo n paroko ibi ranṣẹ si gomina Akeredolu nitori bi o ṣe n duro lai wẹyin fun ominira awọn eniyan rẹ labẹle.
‘’Gomina Akeredolu gangan ni wọn ranṣẹ ibi naa si, ko si ani-ani nipa eleyii’’
‘’Kii ṣe ikọlu to ṣadede waye, iranṣẹ ni wọn fi ṣe, a si ti gbọ wọn daadaa.’’
‘’Nitori naa ni mo ṣe wa nibi lati jẹ ki gomina naa mọ wi pe a gbọ iṣẹ ti wọn ran si wa daradara, lai wẹyin.’’
‘’A ti gbọ iṣẹ wọn, nitori naa ni mo ṣe wa ba gomina naa kẹdun nitori oun ni wọn lo lati ran iṣẹ naa si wa.’’

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Akeredolu ni wọn ro pe wọn le da ipaya si awọn eniyan lọkan amọ ko si ohun to jọ bẹẹ nitori ni bayii ni wọn yoo tun tẹsiwaju lati ma a bu ẹnu atẹ lu gbogbo iwa ibajẹ ti wọn ṣe.
Ogoji eniyan lo ku ninu iṣẹlẹ ikọlu naa, ti eniyan to le ni aadọta si farapa.

















