Naira Marley: Ìjọba fi ìmọ́ Sáyẹ̀ǹsì tan iná wá ìdí owó Naira Marley, ọ̀pọ̀ àṣírí bọ́ sọ́wọ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ agbẹjọ́rò

Ẹka to n ṣiṣẹ lori iwa ọdaran ori ayelujara ni ajọ to n ri si iwa ajẹbanu EFCC ti gbe abọ iwadii wọn ti wọn fi imọ Sayẹnsi ṣe lori ẹsun ti wọn fi kan Azeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley.
Wọn fi ẹsun jija ole kaadi ẹrọ ibanisọrọ kan an to si fojú ba ilé ẹjọ́ giga ti Ikoyi, Eko.
Adari ikọ aṣewadii ijinlẹ Sayẹnsi (Forensic investigation) naa, Whyte Dein sọ fun ile ẹjọ pe iwadii ti ikọ oun ṣe fihan pe olujẹjọ lọwọ ninu jibiti kaadi ibanisọrọ.
Gbajumọ olorin naa, Naira Marley jẹjọ lori oriṣi ẹsun mọkanla to nii ṣe pẹlu jibiti kaadi ibanisọrọ ti wọn ni awọn fura pe o n ṣe eyi to si lodi si abala ofin to de iwa ọdaran ori ayelujara.
Bakan naa ni iroyin sọ pe Naira Marley da awọn ẹsun yii laarin oṣu Kọkanla ọdun 2018 si oṣu Kejila ọdun 2018 ati oṣu Karun ọdun 2018.
Wọn gbe e lọ ile ẹjọ ni Ogunjọ oṣu Karun ọdun 2019 amọ ti wọn gba beeli rẹ.
Bawo ni aṣiri ṣe tu pẹlu imọ Sayẹnsi?
Ẹwẹ, nigba ti igbẹjọ rẹ bẹrẹ pada ni Ọjọbọ, agbẹjọro fun ajọ EFCC, Rotimi Oyedepo sọ fun adajọ agba Nicholas Oweibo pe awọn ri aṣiri ọrọ sisọ lorii ẹrọ alagbeka iPhone olujẹjọ iyẹn Naria Marley pẹlu eeyan kan to n jẹ Raze to n beere fun alaye kaadi ibanisọrọ.
O ni “Ọkan lara iwadii wa pẹlu imọ ijinlẹ Sayẹnsi fihan pasiparọ ọrọ ori foonu pẹlu ọpọ eeyan nigba ti olujẹjọ fi kaadi ibanisọrọ ranṣẹ to fi mọ nọmba ati deeti ti ọjọ yoo lọ lori wọn.
Bakan naa, alaye kaadi Visa wa lara ọrọ ti olujẹjọ fi ranṣẹ si eeyan kan to wa lorii foonu rẹ to n jẹ Raze lẹyin ọrọ yii si ni Raze fi ọrọ ranṣẹ si Marley pada pe kaadi naa ko ṣiṣẹ”.
“A lo irinṣẹ iwadii lati rii pe lootọ ni kaadi ọhun ṣiṣẹ. A wa tun ilana yii kan naa lo nigba keji ti a si rii pe o pada ṣiṣẹ”.

Dein tun ṣalaye pe olorin naa tun lo itakun agbaye elede pupọ fi ṣiṣẹ lori awọn itakun ti ko bofin mu.
O ni: “Olujẹjọ lo oniruuru irinṣẹ ti ko tọ fi bo oju ẹni to n lo ẹrọ ayarabiaṣa nigbakuugba to ba bọ sori ayelujara eyi to fi n ja si awọn itakun to ṣokunkun. Eyi lo fun wa lanfani lati fura si pe olujẹjọ naa n ṣe awọn iṣẹ ti ko tọ pẹlu kaadi ibanisọrọ a si wa ri aridaju eleyi nipasẹ ibeere kan ti a fi ranṣẹ si “Visa Western Union Card”.
O tẹsiwaju pe “iru awọn oju opo to wọpọ lorii itakun to ṣokunkun (dark web) ni oju ọja ti wọn ti n ta awọn ọja ti ko tọ bii oogun oloro, nkan ijagun atawọn kaadi ibanisọrọ ti wọn ji ti wọn si n tun ta”.
“Ibi to tun wa dudu ju ni ibi ti wọn ti n fi owo gba awọn eeyan to n ṣe iṣẹ fayawọ ati ti wọn ti n ṣe pasiparọ ihoho ọmọde”.
Akọṣẹmọṣẹ onimọ ijinlẹ Sayẹnsi mii, Buru Buhari ti sọ latinu oṣu Kẹwa ọdun 2019 lasiko ti wọn wa nile ẹjọ ti ṣaaju sọ fun ile ẹjọ pe iwadii oun ṣafihan awọn kaadi ti wọn ji to wa latọwọ awọn banki ilẹ Yuroopu, lati Amẹrika ati Lati Amẹrika latori ẹrọ ayarabiaṣa olorin yii.
Dein wa sọ ko ọrọ jọ pe awọn iwadii tọka ilọwọ si olujẹjọ ninu iwa ọdaran ori ayelujara amọ ṣa, agbẹjọro fun olujẹjọ, agbẹjọro agba Olaleka Ojo n tako eyi to si ni ile ẹjọ nikan lo le kasẹ ọrọ nilẹ.
Wọn ti sun ẹjọ naa siwaju di ọjọ Kẹtala lati dajọ lori awọn ọrọ ti wọn gbọ ati ọjọ Kẹẹdogun oṣu Keje lati tẹsiwaju ninu ẹjọ naa.















