Naira Marley Vs Mohbad: Mi ò mọ ohun tí mó ṣe tí Naira Marley fi ń wá ikú mi

Oríṣun àwòrán, Legit
Ọ̀kan lára àwọn olórin ilé iṣẹ́ orin tàkasúfèé, Marlian music, Ilerioluwa Oladimeji tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Mohbad ti ké gbàǹjarè pé àwọn ọmọ ikọ̀ orin náà fẹ́ gba ẹ̀mí òun.
Mohbad ní nǹkan aburú bá ṣẹlẹ̀ sí òun, gbajúgbajà olórin tàkasúfèé, Naira Marley àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ló wà nídìí rẹ̀.
Mohbad ké gbàànjarè yìí lóri ẹ̀rọ Instagram rẹ̀ lónìí ní kété tó kúrò ní àhámọ́ àjọ tó ń gbógunti egbògi olóró ní Nàìjíríà, NDLEA.
Ó ní ní kété tí òun darí láti àhámọ́ ni àwọn ọmọ ikọ̀ orin Marlian gbìyànjú láti ṣe òun ní jàmbá.
Nínú fọ́nrán ọ̀hún Mohbad rọ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n ṣàánú òun, òun kò fẹ́ kú báyìí.
Bákan náà ló ní ilé ìwòsàn ni òun ń lọ bí òun ṣe wà nínú ọkọ̀ tó ti ń ṣe fọ́nrán náà.
Kíni Naira Marley sọ?
Naira marley kò ì tíì fèsì sí fọ́nrán tó gba ìgboro kan yìí ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ yìí ló fi léde lórí ẹ̀rọ Twitter rẹ̀ pé NDLEA ti fi Mohbad sílẹ̀ àmọ́ ó ku Zinoleesky ní àhámọ́.
Naira Marley ní ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ òun yìí kò tẹ́ òun lọ́rùn àti pé òun nílò láti padà sí Eko ní kíákíá.
Ó ní ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ìdúnkokò mọ́ òun àti àwọn ènìyàn òun.
Ta ni Mohbad?
Ilerioluwa Oladimeji ní orúkọ tí ìyá àti bàbá rẹ̀ sọ ọ.
Orúkọ ìnagijẹ rẹ ní Mohbad.
Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdún 1996 ni wọ́n bí sí ìpínlẹ̀ Eko, tó sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ní ìpínlẹ̀ Eko bákan náà.
ọdún 2016 ló bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ tó sì wà lábẹ́ ikọ̀ orin Marlian Music tí Naira Marly dá sílẹ̀.














