Tinubu presidency and olubadan visit: Ìyàwó Olubadan tuntun pariwo síta, Òni ọkọ ohun kò gbọ́wọ́ le Tinubu fún ipò ààrẹ lọ́dun 2023

Tinubu, Olubada pẹlu olori olubadan

Oríṣun àwòrán, Insideoyo.com

Iyawo ẹni ti wọn yan gẹgẹ bi Olubadan ti ilẹ Ibadan tuntun, Iyaafin Joyce Anene Balogun ti pariwo sita pe irọ nla lọrọ kan to n lọ kaakiri pe ọkọ oun, Sẹnetọ Balogun fọwọ si oludije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bla Ahmed Tinubu fun ipo aarẹ nibo ọdun 2023.

Oniruuru ahesọ ọrọ lo n lọ kaakiri pe lasiko ti Bọla Tinubu ṣe abẹwo si Olubadan ni ibẹrẹ sẹ yii, toun ati oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ lọdun 2019 labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC, Bayọ Adelabu ni wọn jọ kọwọrin.

Latigbayi wa lawọn kan si ti n gbe iroyin yii

Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin, Olori Anene Balogun ni oniruru ipe loun ti gba lori ago latọdọ awọn eeyan i wọn ni awọn gbọ iroyin ofege naa.

Olori Balogun ni "abẹwo ikiniku oriire pọnbele ni abẹwo Tinubu si ile Olubadan ti wọn ṣẹṣẹ yan, Oloye Lekan Balogun. Irufẹ abẹwo ibeere ara ẹni ti awọn eeyan maa n ṣe si ara wọn naa ni".

Àkọlé fídíò, Akàwégboyè alákàrà

Ki ni Tinubu sọ lọdọ Olubadan?

Nigba to de ọdọ Olubadan ti wọn ṣẹṣẹ fẹ yan sori oye, Agba Oye Lekan Balogun, Sẹnetọ Bọla Tinubu ko fi meni pe meji lori ipinnu rẹ, to si sọ ọ yanya pe ohun gbogbo to ba gba ni oun ṣetan lati fun un, lọna ati le e du ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Aṣiwaju Tinubu ṣalaye pe ohun ṣetan lati ja ija rọfọrọfọ pẹlu ẹnikẹni lọna ati du ipo naa.

O ṣalaye fun Kabiyesi tuntun to fẹ jẹ nilu Ibadan pe ṣiṣe aarẹ lẹyin Aarẹ Muhammadu Buhari jẹ ala kan to ti wa lọkan oun lati ọjọ pipẹ wa, ko si si ẹnikẹni to le e da oun duro mọ.

Tinubu ni: "Ko si idumọhurumọhuru mọni kankan to le di mi lọna. Mo ti ṣetan lati ja ija rọfọrọfọ. Mo ti gbaradi tan bayii lati di aarẹ Naijiria. Ikorita koyemi la wa bayii."

Adelabu pẹlu Olubadan

Oríṣun àwòrán, oyoaffairs.net

Olubadan yonbo Tinubu to n du ipo aarẹ:

Olubadan tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, Oloye Lekan Balogun, nigba to n fesi si ọrọ Tinubu ni odu ni Tinubu, kii sii ṣe aimọ oloko lagbo oṣelu.

"Iwọ lo ṣe ifilọlẹ ipilẹ idagbasoke ipinlẹ Eko ti gbogbo aye mọ loni. O si ko ipa nla lati gbe Naijiria de ibi to wa loni.

Laisi Yoruba, Naijiria ko le e si ni ibi to wa loni. Naijiria ti pin yẹlẹyẹlẹ. Aarẹ lati ilẹ Yoruba ti yoo mu iṣọkan wọ orilẹede yii bayii ni a nilo."

Àkọlé fídíò, Diabetes Ulcer

Ki lo n ṣẹlẹ pẹlu Tinubu ati ipo aarẹ Naijiria?

Ni oṣu kinni ọdun 2022 ni Aṣiwaju Bla Tinubu kọkọ kede pe oun fẹ du ipo aarẹ lẹyin to ṣepade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari tan nilu Abuja.

Aṣiwaju ẹgbẹ Oṣelu APC naa ṣalaye fawọn akoroyin lẹyin ipade naa pe oun wa fi to aarẹ leti ni nipa ipinnu oun lati gbe apoti ibo fun ipo aarẹ lọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Money Ritual: Ǹ kò le bèèrè

Tinubu sọ fun awn oniroyin nigba naa pe afọbajẹ loun tẹlẹ oun si ti ṣetan bayii lati di ọba bẹẹni ko si si ofin kankan to sọ pe afọbajẹ ko le e di ọba.

Bakan naa lo si ti n lọ kaakiri tibu toro orilẹede Naijiria lati igba naa lati fikuluku pẹlu awọn alẹnulọrọ gbogbo.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...