Constitution Amendment: Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ẹni fọnmú lórí ìpinnu aṣòfin àpapọ̀ láti máa gba owó ìfẹ̀yìntì àgbàdọjọ́okú

Sẹnetọ Ahmad Lawan, olori ile aṣofin-ṣoju, Họnọrebu Fẹmi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, HouseNGR

Wo awon koko to jẹyọ nibi ipade lori ọ̀rọ̀ ofin tuntun naa

Abala aba kẹrindinlogun (Recommendation 16) tawọn ọmọ igbimọ atunṣe iwe ofin Naijiria gbe kalẹ naa lo salaye bayii pe:

"Ki ile gba abajade iṣẹ igbimọ pataki lori agbeyẹwo iwe ofin Naijiria tọdun 1999 lori abadofin lati yi iwe ofin apapọ Naijiria tọdun 1999 pada, lati pese aye fun owo ifẹyinti fun awọn adari ile aṣofin apapọ; atawọn nnkan miran to fara pẹ ẹ."

Abala kẹrinlelọgọrin iwe ofin 1999 to wa nilẹ, ti faye silẹ fun owo ifẹyinti agbadọjọ iku fun gbogbo awọn olori orilẹede Naijiria to ti jẹ atawọn igbakeji wọn, eleyi to n na orilẹede Naijiria ni owo to din diẹ ni biliọnu mẹjọ naira lọdọọdun.

Àwọn aṣòfin àpapọ̀ ń gbèrò owó ìfẹ̀yìntì àgbàdọjọ́ọkú fáwọn adarí wọn

Ọrọ pọ to n ti ẹnu awọn eeyan bọ ni Naijiria bayii lẹyin ti awọn aṣofin apapọ fi ofin owo ifẹyinti agbadọjọ iku kalẹ sinu atunto iwe ofin Naijiria ti wọn n ṣe lọwọ.

Awọn ti yoo maa lẹtọ si owo ifẹyinti a-gba-dọjọ-iku naa ni awọn alakoso ile aṣofin apapọ mejeeji atawọn igbakeji wọn.

Sẹnetọ Ahmad Lawan, olori ile aṣofin-ṣoju, Họnọrebu Fẹmi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, other

Bi abala atunṣe iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 yii ba lee ru u la niwaju awọn aṣofin ile, a jẹ wi pe lati ori Aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Ahmad Lawan, olori ile aṣofin-ṣoju, Họnọrebu Fẹmi Gbajabiamila atawọn igbakeji wọn, naa yoo lẹtọ si owo ifẹyinti agbadọjọ iku yii.

Igbimọ tẹẹkoto ti ile aṣofin apapọ gbe kalẹ lati ṣe atunto iwe ofin Naijiria tọdun 1999 lo gbe eyi kalẹ gẹgẹ bi ọkan lara atunṣe mejidinlaadọrin ti wọn gbe kalẹ fin fifi sinu iwe ofin naa.

Sẹnetọ Ahmad Lawan, olori ile aṣofin-ṣoju, Họnọrebu Fẹmi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, HouseNGR

'Ọkan lara awọn ofinimọtaraẹninikan tawọn eeyan to n janfani Naijiria fi n di ẹru idamu le araalu lori niyi'

Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ araalu ti n fọnrere bayii pe ki awọn eeyan o fa awọn aṣofin wọn leti lati maṣe fọwọ si abala naa.

Adari ẹgbẹ ajafẹtọ, Civil Society Legislative Advocacy Centre, CSLAC, Auwal Rafsanjani ṣalaye pe wahala irora nla lawọn adari tun fẹ di le araalu lori bi wọn ba lee gba abala naa wọle sinu iwe ofin orilẹede Naijiria tọdun 1999.

Ọgbẹni Rafsanjani ni iye igbadun ti awọn oloṣelu ti gba lara kosi-kosi araalu ko tii to wọn leyii tumọ si.

Aarẹ Buhari, Sẹnetọ Ahmad Lawan, olori ile aṣofin-ṣoju, Họnọrebu Fẹmi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Housengr

Ki ni abala atunto ofin naa sọ?

O fi kun un pe isinrulu nipo aṣaju wa fun kii ṣe eyi ti wọn fi n ko ọrọ jọ.

'Ọkan lara awọn ofin imọtaraẹninikan tawọn eeyan to n janfani Naijiria fi n di ẹru idamu le araalu lori niyi'

Ajọ ajafẹtọ SERAP ni tirẹ sọ pe kii ṣe asiko yii ti awọn araalu n pariwo pe nnkan ko rọgbọ ati pe iye owo tawọn oloṣelu n ko sapo p ju eyi ti orilẹede yii atawọn eeyan rẹ le fi duro fun idagbasoke, lo yẹ ki awọn aṣofin apapọ tun maa gbe iru ofin bayii dide.

Igbakeji adari SERAP, Kla Dare ṣalaye fawọn oniroyin to fi ọrọ naa lọ ọ pe, "Bo ba jẹ ootọ o. Irufẹ ofin bẹẹ ko lee ṣanfani fun araalu. SERAP ṣi wa nile ẹjọ nibi to ti n tako irufẹ owo ifẹyinti a-gba-dọjọ iku yii ti wọn n san fun awọn gomina ipinlẹ kan atawọn igbakeji wọn."