Policeman dies in Gbenga Daniel‘s House: Àya ọlọ́pàá tó kú ní òun kọ N1m tí wọn fún òun

Oríṣun àwòrán, Gbenga Daniel/Facebook
Ìyàwó ọlọ́pàá tó kú sílé gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Ogun, Gbenga Daniel, ní àwọn kò ni igbàgbọ́ nínú ìròyìn tí wọ́n sọ fún àwọn lórí ohun tó ṣekú pa ọkọ òun.
Abosede Ogunsola, tó jẹ́ ìyàwó sájẹ́ǹtì ọlọ́pàá náà ní àwọn tún kọ owó mílíọ̀nù kan náírà tí wọ́n fún àwọn.
Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ní Adeleke Ogunsola kú sí ilé gómìnà tẹ́lẹ̀ rí náà tó wà ní Sagamu.
- Kí ni Sajẹ́ńtì Ọlọ́pàá lọ ṣe nílé gómìnà Ogun tẹ́lẹ̀ tó tẹ́rí gba ikú?
- Ìjà d'ópin, ogun ti tán! Ẹ wo bí Mide Martins àtí Olamide àbúrò rẹ̀ ti ń ṣàjọyọ̀ oríire
- Ìtàn ayé Shina Rambo, adigunjalè tó fi ahọ́n èèyàn 100 mu ẹ̀kọ́, fi oyún 27 gún ọṣẹ
- Wo ohun tí Jaruma Oníṣòwò “Kayamata” tún ṣe tí wọ́n ń gbé e padà lọ s'ẹ́wọ̀n
- Owó wọgbó l‘Ondo! NDLEA dáná sun oko ìgbó éékà 162 tówó rẹ̀ tó ₦900m
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ileesẹ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fi léde, Adeleke Ogunsola ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ rẹ̀ nígbà tí awakọ̀ Gbenga Daniel ṣèèṣì kọlùú nígbà tó ń ṣí géètì ilé ọ̀hún.
Nígbà tí wọ́n yóò fi dé ilé ìwòsàn, ó si ti jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Ọgbẹ ti mo ri ni aya ọkọ mi nile igbokusi ko yẹ ko pa a - aya oloogbe
Amọ Abosede Ogunsola, nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní, ileesẹ ọlọ́pàá àti amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Gbenga Daniel sọ fún òun pé irin kan ló jábọ́ lé ọkọ òun láyà, tó sì ṣekúpa á.
Ṣùgbọ́n ó ní nígbà tóun dé yàrá ìgbókùúpamọ́sí tí ọkọ òun wà, ọgbẹ́ tí òun rí láyà rẹ̀ kìí ṣe èyí tó lè pá.
Ó fi kun pé àwọn mọ̀lẹ́bí ti ń ṣe àṣàrò lórí bí wọn yóò ṣe ṣe àyẹ̀wò òkú ọkọ òun láti fi ìdí òótọ́ ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ múlẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣókùnkùn sí ẹ̀dá kedere ni níwájú Ọlọ́run.
Wọn fun mi ni miliọnu kan naira amọ mo kọ lati gba?
Abosede ni lóòótọ́ ni wọ́n fún àwọn ni mílíọ̀nù kan náírà lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sọ ẹni tó gbé owó náà kalẹ̀, àmọ́ o ni àwọn kò gbà á.
Ó ṣàlàyé pé láti ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ṣwaye ni Satide, ọjọ́ Ajé ni wọ́n tó yọjú sí àwọn.
"Kìí ṣe pé wọ́n fún wa ní owó náà ní ilé wa, lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀ tí wọn lọ tán, ni DPO pè wá pé àwọn gbé mílíọ̀nù kan náírà wá."
"Ẹ̀gbọ́n ọkọ mi wá béèrè pé kí ni owó náà wà fún?
Ṣé láti fi rán àwọn ọmọ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ni tàbí láti fi dá àwọn ìyàwó lókoòwò? Tó sì ní kí wọ́n jẹ́wọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan.
Ìwádìí ọlọ́pàá:
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Premium Times ṣe sọ, ọlọ́pàá kan tí kò fẹ́ kí àwọn akọ̀ròyìn dárúkọ òun nítorí kò ní àṣẹ láti sọ̀rọ̀ ní, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ọlọ́pàá ń ṣe ìwádìí rẹ̀ tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó ní kí wọ́n yi sí pé Adeleke kú sẹ́nu iṣẹ́.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò sí níbẹ̀, ó ní àwọn tọ́rọ̀ náà ṣojú wọ́n ní kìí ṣe ìjàm̀bá ọkọ̀ ló wáyé.
Ó fi kun pé nígbà tí àwọn nawọ́ gán awakọ̀ náà, tí àwọn ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún un, IPO tó wà nídìí ẹjọ́ yìí ti fẹ́ fi ẹjọ́ ìpànìyàn kàn án kí wọ́n tó ráńṣẹ́ látòkè pé àwọn kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.
Ó ní àwọn tí ń gbọ́ pé àwọn ènìyàn gómìnà àná náà ti ń bèèrè fún sísọ ọ̀rọ̀ náà ní tùbí ǹ nùbí, tí wọn kò bá ní ẹbọ lẹ́rù, kò yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
Kí ni Agbẹnusọ ọlọ́pàá sọ?
Agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ní ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.
Oyeyemi ni òun kò mọ̀ nípa pé wọ́n fún àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé ní owó mílíọ̀nù kan náírà.
Kí ni Gbenga Daniel sọ?
Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Ogun, Gbenga Daniel ni òun kò sí nílé nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Steve Oloyede fi síta ní Gbenga Daniel kò sí nílé nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
O ni oun pasẹ pe kí wọ́n gbé lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú ṣùgbọ́n tó bá isẹlẹ naa lọ.
Ó ní ìwádìí ti ń lọ lọ́wọ́, tó sì gbàdúrà kí Ọlọ́run rọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lójú.
Bákan náà ló fi kún pé ileesẹ ọlọ́pàá nìkan ló le sọ ohunkóhun nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Kí ni Sajẹ́ńtì Ọlọ́pàá lọ ṣe nílé gómìnà Ogun tẹ́lẹ̀ tó tẹ́rí gba ikú?

Oríṣun àwòrán, Facebook/Gbenga Daniel
Saaju la ti mu irpyin wa fun yin pe Sajẹnti Ọlọpaa, Adegoke Ogunsola ti kú si ile gomina Ìpínlẹ̀ Ogun tẹ́lẹ̀ rí, Otunba Gbenga Daniel.
Alukoro Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ náà, Abimbola Oyeyemi fi aridaju iṣẹlẹ náà hàn fún àwọn oniroyin lọ́jọ́ Aje.
Agbẹnusọ Ọlọpaa náà ṣàlàyé pé wọn pin Ogunsola si ile Otunba Daniel níbi ti wọn tun máa n pe ni Asoludero Court ni ilu Sáàmù láti lọ ṣiṣẹ́ ni.
Nigba to n ṣàlàyé nípa iṣẹlẹ náà to waye lọjọ Abameta to kọjá, Oyeyemi ṣàpèjúwe ikú Sajẹnti yìí gẹgẹ bii eyi to ṣèèṣì to sì lè sẹlẹ si ẹnikẹni.
- Sotitobire: Ẹ wá wo ohun t'Ọ́lọ́run ń ṣe ní ìjọ mi lẹ́yìn tí mo bọ́ ní ẹ̀wọ̀n gbére tẹ́ẹ tì mí lọ
- Obinrin mínísítà Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí ẹ̀wọ̀n he fẹ́sùn ṣíṣe owó kúmọkùmọ
- Adájọ́ fi ọ̀sẹ̀ méjì kún àkòkò tí Abba Kyari yóò lò ní àhámọ́ NDLEA
- Báwo ní olóyè ìlú kan ti ṣe, tí orun kàyéfì fi kun àwọn ajínigbé tó mu nígbèkùn l‘Ondo?
- À ń ri òkú ọmọdé, òògùn olóró àti ẹ̀yà ara èèyàn lórí àkìtàn lọ́sọ́ọ̀sẹ̀ - Akódọ̀tí
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
Gẹgẹ bo ṣe sọ fún Ileeṣẹ ìròyìn Channels TV, Ọlọpaa naa n gbiyanju lati ṣi ilẹkun ibodè ile naa ni ki ọkọ to gba a lasiko naa.
Agbenuso Ọlọpaa ni wọn sare gbe Sajẹnti náà dìgbà dìgbà lọ ile iwosan ṣùgbọ́n ti pada sọ pe o ti jẹ Ọlọ́run nipe.
Otunba Gbenga Daniel ni Gomina Ìpínlẹ̀ Ogun laarin ọdun 2003 si 2011 lábẹ́ Asia ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP).





















