Sara Ochepe: Ilé ẹjọ́ sọ Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí àtàwọn méjì mìí sí ẹ̀wọ̀n

Sarah Ochekpe

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ilé ẹjọ́ gíga tó fi ìlú Jos, ìpínlẹ̀ Plateau ṣe ibùjókòó ti sọ Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí lórí ètò omi, Sarah Ochekpe àti àwọn méjì mìíràn sẹ́wọ̀n ọdun mẹ́fà fún ẹ̀sùn màkàrúrù irinwó lé àádọ̀ta mílíọ̀nù náírà.

Ochekpe tó ṣe Mínísítà lásìkò ìjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan, ní ilé ẹjọ́ sọ òun, alága àná ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) ìpínlẹ̀ Plateau, Raymond Dabo àti ẹni tó jẹ́ alákosó ìpolongo ètò ìdìbò Jonathan, Leo-Sunday Jitong sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta.

Ní ọdún 2018 ní àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu EFCC fẹ̀sùn ṣíṣe owó kúmọkùmọ àti lílẹ̀dí àpòpọ̀ kan àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta.

Ẹ̀wẹ̀, Ochekpe, Dabo àti Jitung ti ní àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn.

Àkọlé fídíò, Money Ritual: Ǹ kò le bèèrè

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, Onídàjọ́ Musa Kurna ní àwọn afẹ̀sùnkàn náà jẹ́bi gbígba owó irinwó lé àádọ̀ta mílíọ̀nù náírà ní ilé ìfowópamọ́ léyìí tó ju owó tí ẹnìkan ní àǹfàní láti gbà lọ.

Kurna ní lẹ́yìn tí wọ́n gba owó náà ní ilé ìfowópamọ́, olùdíje sí ipò gómìnà kan ni wọ́n ko owá náà fún, léyìí tó túmọ̀ sí pé wọ̀n kò jẹ̀bi kíkó owó náà dání.

Bákan náà ló ní ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ yìí tako òfin ìṣowó kúmọkùmọ ọdún 2013 tí ìjìyà rẹ̀ sì jẹ́ lílọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà tàbí sísan owó ìtanràn mílíọ̀nù mẹ́wàá.

Ta ni Sarah Ochekpe?

Ọmọ bíbí ìlú Foron, ìjọba ìbílẹ̀ Barkin Ladi ní ìpínlẹ̀ Plateau ni Sarah Reng Ochekpe.

Ní ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹwàá, ọdún 1961 ni wọ́n bi sínú ẹbí Reng Madugben.

Ní ilé ẹ̀ka gíga Fásitì Ahmadu Bello Zaria ló ti gba oyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ ètò òṣèlú.

Sarah Ochekpe ti di oríṣìíríṣìí ipò mú ní National Orientation Agency níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ ṣaájú kó tó di Mínísítà lọ́dún 2011.

Láàárín ọdún 2011 sí ọdún 2015 ló fi ṣe Mínísítà lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan.