Ọmọ ọdún mẹ́jọ tú àṣírí f'áwọn ọlọ́pàá bí bàbá rẹ̀ ṣe fún ìyá rẹ̀ lọ́rùn pa

Oríṣun àwòrán, Ogun Police
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti fi ṣìkún òfin gbé ọkùnrin, ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta kan, Oluranti Badejo fẹ́sùn wípé ó lu ìyàwó rẹ̀, Folasade Badejo, ẹni ogójì ọdún dójú ikú.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lọ́jọ́bọ̀ ní àbúrò olóògbé náà ló lọ fi ẹjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Mowe.
Oyeyemi ní ọmọ olóògbé náà ló pe àbúrò ìyá rẹ̀ wí pé bàbá àwọn ti lu ìyá òun pa ní ilé wọn tó wà ní ojúlé Keje, òpópónà Madam Felicia, Orimerunmu Mowe, ìpínlẹ̀ Ogun.
Àtẹ̀jáde náà ní nígbà tí àbúrò olóògbé náà fi ẹjọ́ náà sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá ọ̀hún ni DPO ibẹ̀, SP Folake Afeniforo rán àwọn ọlọ́pàá lọ sí ilé náà tí wọ́n sì nawọ́ gán afurasí náà.
Ó fi kun pé àwọn bá òkú obìnrin náà nílẹ̀ nígbà tí wọ́n dé ilé náà tí àwọn sì ti gbe lọ sí ilé ìgbókùsí ní ìlú Shagamu fún àyẹ̀wò tó péye.
Oyeyemi ṣàlàyé pé ìwádìí àwọn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé afurasí náà fún ìyàwó rẹ̀ lọ́rùn pa nígbà tí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn méjéèjì.
Ó tẹ̀síwájú pé nígbà tí afurasí náà ti ri pé ìyàwó òun ti jẹ Ọlọ́run nípè ló bá fi àyọ̀nù ìlọṣọ gbígbóná jó ìyàwó rẹ̀ lára kí ó le dàbí pé iná ló gbé obìnrin náà tó fi kú.
Báwo ni àṣìrí Oluranti Badejo ṣe tú?
Nígbà tí gbogbo ìjà àti bí Oluranti Badejo ṣe fún ìyàwó rẹ̀ lọ́rùn pa ṣe ń lọ lọ́wọ́, ọmọ wọn, ọmọ ọdún mẹ́jọ wà nínú ilé tó sì rí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ọmọ wọ́n yìí ló wà ṣàlàyé gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn ọlọ́pàá láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.
Àtẹ̀jáde náà fi kún un pé ọmọ yìí ló sọ fún àwọn ọlọ́pàá bí bàbá rẹ̀ ṣe fi áyọ̀nù jó ìyá rẹ̀ lára láti fi parọ́ pé iná ló gbé ìyàwó òun.
Bákan náà ló fi kún un pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Ogun, Lanre Bankole ti wá darí kí wọ́n gbé ẹjọ́ afurasí náà lọ sí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwádìí ìwà ọ̀daràn fún ìwádìí tó péye.
Ó fi kun pé ní kété tí ìwádìí àwọn bá ti parí ni àwọn yóò gbé afurasí náà lọ sí ilé ẹjọ́ láti lọ kojú ìgbẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn tó ń kojú.















