Legiiti ni, confam! 'Bí mo ṣe rí orúkọ mi ‘MC Remote’ rèé o!'
Gbajugbaja apanilẹrin lori ayelujara Tolulope Olayiwola ti ọpọ mọ si MC Remote ba BBC Yoruba sọrọ bi o ṣe n tiraka lati ibẹrẹ titi to fi di ilumọọka.
“Mo ṣaa mọ pe mo dede jẹ alawada eeyan ti awọn eeyan a maa rẹrin bi mo ba sọrọ, bi emi naa ṣe ni ki n dan an wo niyẹn ti mo si bẹrẹ ni ṣọọṣi.
Alinko ni wọ́n ń pè mi ní ilé ẹ̀kọ́ girama àmọ́ mo padà di Remote. Tolulope ṣalaye pe ibi eto kan naa lawọn lọ ti oun si wa lara awọn ti yoo ṣe ẹfẹ nibẹ.
Ni wọn ba wa beere pe ki ki awọn kọ sinu iwe gẹgẹ bi orukọ rẹ. “Mo ni mo n bọ ẹ maa lọ na, nigba ti wọn wa ni ẹlẹẹkẹta pe awọn ti fẹ fun atọkun eto ni iwe naa ni mo ni o daa, ẹ kọ “Remote” sii”.
Fun alẹ yẹn nikan ni ero tirẹ tẹlẹ pe ki oun yii pada to ba ya afi ti gbogbo eeyan baa gbaa ni orukọ ori itage rẹ eyi ti gbogbo aye mọọ si titi di oni yii.













