Ìyanṣẹ́lódì ASUU kò gbọdọ̀ wáyé mọ́ ní Naijiria – Gbajabiamila

Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, @okunolahope

Agbẹnusọ ile igbimọ aṣojuṣofin, Femi Gbajabiamila ti sọ pe gbogbo awọn ti ọrọ eto ẹkọ kan ni Naijiria gbọdọ ṣe ohun to yẹ ki iyanṣẹlodi ẹgbẹ oṣiṣẹ fasiti, ASUU, le di ohun igbagbe.

Gbajabiamila lo sọ ọrọ naa lẹyin ti ASUU wọgile iyanṣelodi wọn to gbẹnule oṣu mẹjọ.

Iyanṣẹlodi ọhun waye latari oniruru ẹtọ ti awọn olukọ naa n bere fun lọwọ ijọba apapọ.

Nigba to n dupẹ lọwọ ijọba apapọ ati ASUU fun bi iyanṣẹlodi naa ṣe pari, agbẹnusọ naa ni asiko ti to lati wa ojutu si iṣoro to n koju ASUU.

O ni o ṣeni laanu pe iyanṣẹlodi naa waye fun oṣu mẹjọ gbako, amọ ko tilẹ yẹ ki iyanṣẹlodi ọhun waye rara.

Gbajabiamila sọ pe “Awọn fasiti wa gbọdọ jẹ ibi ti awọn ọdọ yoo ti mọ irufẹ ẹni ti wọn jẹ ki wọn si le gbe ohun rere ṣe nile aye.”

Lẹyin naa lo ke si jọba, ASUU atawọn ẹgbẹ mii ti ọrọ kan lati wa nnkan ṣe si ọrọ eto ẹkọ nitori ọjọ ọla awọn akẹkọọ.

Gbajabiamila wa lara awọn to da si iyanṣẹlodi naa, pẹlu awọn aṣofin mii ko to niyanju.

Lẹyin ti Buhari ba igbimọ Gbajabiamila ṣe ipade nigba meji ọtọtọ lọsẹ to jọja, wọn yanju ọrọ naa laarin ASUU ati ijọba apapọ.

Wayi o, bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ko tii ṣe ohun gbogbo ti ASUU n bere fun, o ṣetan lati ṣe lara awọn ohun ti wọn n fẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Ìjọba kò ì tíì dáhùn àwọn ìbéèrè wa, àṣẹ ilé ẹjọ́ ló mu wa wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì - ASUU

Àworan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, ASUU ti ní kìí ṣe wí pé àwọn finú fẹ́dọ̀ wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì tí àwọn gùnlé bíkòṣe wí pé àwọn kò fẹ́ kó àṣẹ ilé ẹjọ́ dànù.

Ààrẹ ASUU, Emmanuel Osodeke ló sọ bẹ́ẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Ẹtì.

Osodeke nínú àtẹ̀jáde náà nítorí ẹ̀bẹ̀ Ààrẹ Muhammadu Buhari àti Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, Femi Gbajabiamila, ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn àtàwọn eèkàn ìlú mìíràn tó bá àwọn ni àwọn ṣe ń padà sẹ́nu iṣẹ́ báyìí.

Ó ní níwọ̀n ìgbà tí Mínísítà fọ́rọ̀ òṣìṣẹ́, Chris Ngige ti gbé àwọn lọ sí ilé ẹjọ́ láti ìgbà tí ASUU tí kéde ìyanṣẹ́lódì aláìnígbèdéke lọ́jọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹjọ, ọ̀rọ̀ ṣì ń lọ lórí gbogbo ohun tí àwọn ń bèèrè fún.

Kí ni ASUU ń bèèrè fún?

Àtẹ̀jáde ASUU

Oríṣun àwòrán, ASUU

Àtẹ̀jáde ASUU

Oríṣun àwòrán, ASUU

Ààrẹ ASUU ṣàlàyé pé àwọn nǹkan tí àwọn ń bèèrè tí àwọn fi gùnlé ìyanṣẹ́lódì náà ni wí pé ni:

  • Kí ìjọba fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ fásitì lówó láti ṣàtúnṣe àwọn ilé ẹ̀kọ́ wọ̀nyí
  • Fífún àwọn olùkọ́ ní owó àjẹmọ́nú lásìkò
  • Ṣíṣe ìdásílẹ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì tó jẹ́ ti ìjọba lọ́pọ̀ yanturu
  • Lílo UTAS láti fi máa san owó oṣù àwọn olùkọ́ àti láti fi ṣe àyẹ̀wò nǹkan tó ń fa kùdìẹ̀kudiẹ nínú owó oṣù àwọn olùkọ́
  • Ṣíṣe àtúngbéyẹ̀wò àdéhùn tí ìjọba àpapọ̀ àti ASUU fẹnukò lé lórí lọ́dún 2009

Ó ní gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìjọba kò ì tíì dá àwọn lóhùn lé lórí bó ṣe yẹ.

ASUU ti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì olóṣù mẹ́jọ

Fasiti Eko

Oríṣun àwòrán, Google

Nigbẹyin-gbẹyin, ẹgbẹ awọn olukọ Fasiti ni Naijria ẹka ASUU ti fopin si iyanṣẹlodi ti wọn ti gunle lati oṣu mẹjọ bayii amọ wọn tun fi kọndisọn lee lori.

Awọn ileeṣẹ iroyin to ti ba aṣoju ASUU sọrọ̀ jẹ ko di mimọ pe ọkan lara wọn lo fun awọn ni aridaju naa.

Ẹwẹ, ileeṣẹ BBC ti ba igbakeji aarẹ ẹgbẹ ASUU, Ọmọwe Chris Piwuna sọrọ to si fi aridaju rẹ han fun wọn pe wọn ti soo rọ.

O sọ fun wa pe ni owurọ oni ni awọn fopin sii lẹyin ipade ti awọn ṣe ni Abuja lati alẹ wọ oru mọjumọ aarọ kutukutu yii.

Ile ẹjọ giga julọ lorilẹede Naijiria ti paṣẹ yii fun ASUU pe ki wọn fopin si iyanṣẹlodi naa ki wọn tilẹ to lee gbọ ẹjọ kotẹmilọrun wọn rara.

Ni ọjọ Kẹrinla Oṣu Keji ọdun yii ni awọn olukọni Fasiti kaakiri Naijiria bẹrẹ iyanṣẹlodi yii ti awọn si n ro pe ko ni pẹ amọ idakeji rẹ ni gbogbo ọmọ Naijiria ri o tori ASUU n pe fun ki ijọba pese ohun ti awọn n fẹ eleyii ni wọn dẹ ṣi duro gbagba lori rẹ.