Bàbálọ́jà Ora-Igbomina kò ṣẹ̀ mi, ohun tó ṣe rèé, tí mo ṣe fi àdá gun níkùn – Afurasí

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Bàbálọ́jà Ora-Igbomina fẹ́ gba ilẹ̀ tó fún mi láti dáko lẹ́yìn ọdún kan, ní mo ṣe fi àdá pa á – Afurasí

Aworan Afurasi

Oríṣun àwòrán, Osun Police

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti tẹ awọn afurasi meji to ṣeku pa Babaloja ti Ora-Igbomina, Oloye Oladepo Asaolu, ti wọn si jẹwọ idi ti wọn fi gbe igbesẹ naa

Awọn afurasi meji naa, Sunday Johnson ati Obisesan Amos, ti ọpọ mọ si Ibadan sọ fun awọn akọroyin niluu Osogbo pe awọn mejeeji lẹdi apo pọ lati ṣeku Babaloja naa.

Johnson, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, ni awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti oloogbe naa fi ilẹ ta oun lọrẹ sugbọn awọn si nifẹ lati gba awọn ilẹ miiran lọwọ rẹ.

O ni “ Mo ṣeku pa Oloye Oladepo Asaolu lẹyin to fun mi ni ilẹ lati ma lo lọfẹ sugbọn wọn ni ti nnkan ba ti dara fun mi, awọn yoo gba ilẹ naa padalọwọ mi.

"Ada ti Baba mu dani wa si oko naa ni mo fi gun wọn nikun.

"Mo fi ada gun baba ni ikun tori wọn ni ko si aye mọ lati maa lo oko wọn fun ohun ọgbin"

Afurasi naa tẹsiwaju pe "Baba ti sọ fun mi pe a n lọ si oko ni owurọ ni dede ago marun un kọja isẹju diẹ.

Mo gbe wọn si ori ọkada mi, ti a si gbe ẹnikeji mi dani loju ọna.

"Bi a ṣe de si oko ni Baba ni ko si aye mọ lati ma lo oko wọn fun ohun ọgbin, ti baba si mu ada dani, mo gba ada lọwọ baba, mo si fi gun wọn nikun.

"O ti to ọdun kan ti Baba ti fun mi ni oko naa, ti mo si n fi da oko ọgẹdẹ, obi ati agbado, sugbọn baba ni ti nkan ba ti da awón yoo gba oko naa lọwọ mi.

"O dun mi pe mo pa Baba, emi ko salọ, ile mi ni awọn ọlọpaa ti wa mu mi wa si agọ wọn."

Nigba ti wọn bi Johnson pe ki ni ẹsẹ oloogbe naa, to fi gbe gbesẹ naa, o ni Oloye Oladepo Asaolu ko sẹ oun ni ẹsẹ kankan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ni iwadi fihan pe aya ni wọn ti gun oloogbe naa, ko to jade laye.

Wọn ni awọn afurasi naa lo mu awọn ọlọpaa lọ sinu oko igbo Akisa nibi ti wọn ti sisẹ ibi naa.

Bàbá fún ọmọ rẹ̀ ẹni ọdún 13 lóyún ní ìpínlẹ̀ Ogun, ó ní èèdì ni!

Man impregnates teenage daughter in Ogun

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi

Ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Mfon Jeremiah, ti ko si gbaga ọlọpaa ipinlẹ Ogun lori ẹsun pe o fun ọmọ ara rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹtala loyun.

Afurasi naa, to n gbe ni FIRRO Estate, ni adugbo Adesan, to wa nilu Mowe sọ pe iṣẹ aye ni iṣẹlẹ naa jẹ.

Ọwọ ọlọpaa tẹ afurasi ọhun lẹyin ti wọn fi ọrọ rẹ lọ ni agọ wọn to wa ni Mowe.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ naa, Abimbola Oyeyemi fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni iya ọmọ naa lo fi ọrọ naa lọ lagọ awọn.

O ni “Obinrin naa ṣakiyesi pe ọmọ rẹ ti loyun, nigba to bẹrẹ lọwọ ọmọ naa ẹni to fun loyun, o dahun pe baba oun ni.”

“Lẹyin naa ni wọn gbe ọmọ ọhun lọ sile iwosan fun ayẹwo ti wọn si ṣakiyesi pe oyun oṣu mẹrin ti wa ninu rẹ.”

Eyii lo mu ki wọn fi ọlọpaa ṣọwọ sile ọkunrin ọhun lati fi ṣikun ofin mu lati wa sọ tẹnu rẹ.

Iṣẹ aye ni – Afurasi

Nigba ti wọn bere lọwọ afurasi naa bi ọrọ oyun ọmọ rẹ ṣe jẹ o ni eedi lo de oun ti oun fi ki ọmọ naa mọlẹ.

Oyeyemi ni “O ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe oun la ala pe oun n ba iyawo oun lopọ amọ o ti bọ sori ki oun to mọ pe ọmọ ara oun gan ni oun ki mọlẹ.”

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti paṣẹ ki wọn tare afurasi naa lọ si ẹka to n ri si ọrọ awọn ọmọde fun iwadii ni kikun, ko si le tete foju bale ẹjọ laipẹ.