"N kò le wo dígí torí bí àrùn ‘scleroderma’ tó ba ẹwà mi jẹ́"

Àrùn tí kò gbóògùn, kí Ọlọ́run má fi ṣe wá.
Nígbà tí wọ́n bí Violet, kò ní àrùn kankan lára, tí inú rẹ̀ sì ń dùn pé òun ń dàgbà dada.
Ní ọjọ́ kan ni wọ́n ṣàdédé sọ fún Violet pé ó ní àìsàn kan tí kò gbóògùn, tí èyí sì ti ń da omi tútù sọ́kan rẹ̀.
Àrùn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sclerodema ni wọ́n ní ó ń bá Violet fínra.
Sclerodema tí wọ́n tún ń pè ní systemic sclerosis jẹ́ àrùn to máa ń mú ẹran ara le koko.
Àwọn obìnrin ni àrùn yìí sábà máa ń ṣe ju ọkùnrin lọ.
Báwo ni àìsàn yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ fún Violet?
Violet tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, nígbà tó ń bá BBC sọ̀rọ̀ ní lásìkò tí òun parí ipele ọdún méjì àkọ́kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ìpínlẹ̀ Delta, ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ si òun.
Ó ní àmì dúdú kan ni òun kọ́kọ́ rí, tó yọ sí òun ni ẹ̀yìn, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọwọ́ òun náà bẹ̀rẹ̀ sí ní dúdú pátápátá.
Ohun tí Violet kò mọ̀ ni pé àwọn àmì yìí jẹ́ àpẹẹrẹ àrùn tí kò gbóògùn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé si lára.
Ó sọ pé bí àrùn yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní dàgbà sí òun lára, ni gbogbo ẹ̀yà ara òun bẹ̀rẹ̀ sí ní yàtọ̀, tí òun kò sì jọ ara òun mọ́.
Ó fi kun pé àrùn yìí ti mú kí òun wà nínú ìrònú gidi.
"Mi ò kí le wo dígí nítorí àyípadà tó ti débá ojú mi fún ọjọ́ pípẹ́ àmọ́ nígbà tó yá mo gba kádàrá, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ràn ara mi padà."
"Mo di ẹni tí ó ń ti ara rẹ̀ mọ́lé, èmi tó jẹ́ wí pé iṣẹ́ arìnrìn oge ló wù mí, mi ò lè tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ mi gan."
Àwọn dókítà ní àrùn tó ń ṣe mí kò ní oògùn ṣùgbọ́n mo ní ìgbàgbọ́ pé máa rí ìwòsàn lọ́jọ́ kan

Violet àtàwọn òbí rẹ̀ ní kò sí ibi tí àwọn kò fẹ́ẹ̀ rìn dé láti wá ìwòsàn sí àrùn yìí.
Ó ní bí àwọn ṣe ń lo ti ilé ìwòsàn, ni àwọn n ló ti ìbílẹ̀ ṣùgbọ́n kò sí ẹni tó mọ oògùn tí òun le lò sí àìsàn tó ń bá òun fínra.
Ó fi kún pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ìwòsàn àti ti ìbílẹ̀ tí àwọn kọ́kọ́ lọ, jẹ́ kó yé àwọn pé àwọn kò rí nǹkan tí ó ń ṣe òun.
Ṣùgbọ́n ní báyìí ilé ìwòsàn ti ìjọba Ìpínlẹ̀ Delta ló ti ń gba ìtọ́jú.
Ó ní òun ní ìrètí pé òun máa gbádùn lọ́jọ́ kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn dókítà ni àrùn tó ń ṣe òun kò gbóògùn.
Àwọn ènìyàn ni mo máa ń wú àwọn lórí
Violet tó gbajúgbajà lórí ẹ̀rọ ayélujára TikTok máa ń lo ojú òpó rẹ̀ láti fi ṣe kóríyá fún àwọn ènìyàn. Ó ní àwọn ẹlòmíràn máa ń bú òun síbẹ̀ àwọn mìíràn máa ń kan sárá sí òun. Ó fi kun pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló máa ń fi ìfẹ́ hàn sí òun lórí ẹ̀rọ náà.
"Àwọn ènìyàn máa ń kọ àtẹ̀jísẹ́ sí mi pé mò ń wú àwọn lórí."
Kí ni Sclerodema?
Àrùn Sclerodema jẹ́ àrùn tó máa ń mú ara ẹran ènìyàn le.
Ó jẹ́ èyí tó le ṣàkóbá fún ẹ̀yà tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ kiri nínú ara, àwọn aràn inú àti ti oúnjẹ.
Kò sí ìwòsàn fún àrùn yìí ṣùgbọ́n ìtọ́jú wà láti jẹ́ kí ó má ṣe ara lọ́ṣẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ.
Kò sí ẹni tí kò lè ní scleroderma ṣùgbọ́n ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn obìnrin ju ọkùnrin lọ.












