Seyi Makinde sọ ìdí tó ṣe nira láti fáwọn èèyàn lówó látinú àpò rẹ̀ lẹ́yìn tó di gómìnà

Olówó ní mi tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mò di gómìnà, mó tí di aláìní - Makinde

Aworan GominA Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/OfficialSeyiMakinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti kede pe ni kete ti oun bọ sipo gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Oyo ni oun ti di alaini.

Apo asunwọn owo oun si yatọ si bi oun ṣe wa tẹlẹ, ki wọn to dibo yan oun lọdun 2019.

Makinde sọ eleyi nigba to gba alejo awọn olori akẹkọọ kaakiri ipinlẹ Oyo lọjọ Ajẹ ọsẹ yii.

O ni gẹgẹ bii gomina, owo ti oun gba losu jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalelẹgbẹta o din mẹwa naira (N650,000) to si ti sọ oun di alaini.

“Fun emi, anfani ti n ba ri lati fi fun awọn eeyan ni nkan pada ni maa ṣe.

A kọbi ara si awọn anfani ti yoo jade fun awọn ọdọ eyi ti yoo pọ jaburata fun onikaluku.

“Ki n to di gomina, olowo ni mi sugbọn kete ti mo bọ si ori ipo gomina, mo di alaini.

Owo osu mi gẹgẹ bi gomina jẹ ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun lọna ọtalelẹgbẹta o din mẹwa naira losu (N650,000).

Aworan Seyi Makinbe

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/OfficialSeyiMakinde

N kò le fawọn eeyan ni ẹbun latinu apo mi tori owo tasọrẹ

“Ọkan lara awọn nkan ti n ko fi ni anfani lati fun awọn eeyan ni nnkan lati nu apo mi niyẹn.”

Makinde wa ṣe ileri fun awọn akẹẹkọ pe ijọba oun ṣetan lati gbọ gbogbo awọn ẹdun ọkan awọn akẹkoọ, ki ijọba si mu wa si imusẹ.

“Mo ti tẹti si awọn ẹdun ọkan yii, ti ma si wo finifini lati ri pe gbogbo ẹ wa si imusẹ.

“A wa n ṣe ileri fun awọn akẹẹkọ pe ijọba ti ṣetan lati ṣe gbogbo ohun to tọ lati ṣe gbogbo nikan ti yoo kari awọn akẹkọọ ni ipinlẹ Oyo.”

O ni ijọba oun ti ṣetan lati ba awọn akẹkọọ sisẹ pọ lati mu idagbasoke ba ipinlẹ Oyo.

Makinde tun ṣe ileri pe ijọba yoo fi ilẹ ta awọn akẹkọọ maa lọrẹ lati fi kọ ile ẹgbẹ wọn.

O ni apo ara oun ni oun yoo ti fun awọn akẹkọọ naa lowo lati kọ ile ẹgbẹ akẹkọọ naa.

Àwọn adigunjalè yìnbọn lù mí àmọ́ kò dún mí, mo gba ìbọn lọ́wọ́ wọn - Olubadan

Olubadan Lekan Balogun

Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oba Lekan Balogun yoo se ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrin ọdun rẹ loke eepẹ lọla ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹjidinlogun osu Kẹwa.

Bi Olubadan se wa n mura ọjọ ibi naa, o ti sọ nipa ọpọ iriri to ri loke eepẹ lati ọgọrin ọdun sẹyin paapaa bi awọn adigunjale ṣe kọlu lọpọ ọdun sẹyin.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin lopin ọsẹ, Olubadan ni to ba jẹ pe awọn adigunjale naa ṣe aṣeyọri ni, oun ki ba ma ti gori itẹ Olubadan ti oun wa bayii.

Ninu ọrọ naa, o ni ọdun 1989 ni iṣẹlẹ naa waye nile epo bẹntiro kan niluu Ibadan.

"Mo gba ibọn lọwọ adigunjale, wọn yinbọn lu mi - Ọba Lekan Balogun"

Olubadan Lekan Balogun ṣalaye pe awọn adigunjale naa gbiyanju lati gba gbogbo ohun to wa lọwọ oun, to fi mọ ọkọ oun ṣugbọn oun kọ jalẹ.

O ni “Wọn yibọn lu mi amọ ko dun mi nitori mo gbiyanju lati gba ibọn ilewọ ọwọ wọn.”

“Awọn eeyan to wa layika gbe mi digba digba lọ sile iwosan aladani kan nibi ti wọn ti tari mi lọ si UCH fun itọju pajawiri.”

“To ba jẹ pe wọn ti ṣe aṣeyọri ninu igbiyanju wọn lọdun naa lọhun ni, ipade wa oni ki ba ti waye.

“Idi ree ti mo fi maa n sọ pe ti awọn Musulumi ba n gbadura nigba marun un lojumọ, o yẹ ki n ma gbadura nigba marundinlogun,.

Bakan naa ti awọn ọmọlẹyin Kristi ba n lọ sile ijọsin wọn lẹẹkan laarin ọsẹ, ojojumọ lo yẹ ki n maa lọ.

"Mi o lero mo le de ipo Olubadan, ipo gomina tabi ipo Aarẹ ni afojusun mi"

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ko gbagbọ pe oun yoo de ori itẹ Olubadan, amọ Ọlọrun jẹ ko ṣeeṣe.

O ni afojusun oun gẹgẹ bii oloṣelu ni lati di gomina ipinlẹ Oyo tabi Aarẹ orilẹ-ede Naijiria.

Olubadan sọ siwaju si pe oun ko gbero lati di Mọgaji ni agboole Aliwo, amọ ẹgbọn baba rẹ kan lo kọ jalẹ pe o gbọdọ ṣe ojuṣe rẹ, bo tilẹ jẹ pe o ṣi kere pupọ lọdun naa lọhun.

Ọba Balogun ni “Ore ọfẹ Ọlọrun ni pe mo tilẹ dagba pe ẹni ọgọrin ọdun.”

“Mo si gbagbọ pe mo maa wọ iwe itan gẹgẹ bii Olubadan akọkọ ti yoo gbe inu aafin tuntun ni Oke-Aremo niluu Ibadan.”

Ọba Lekan Balogun ni Olubadan kejilelogoji, ọdun 1942 si ni wọn bi.