Ooni Ogunwusi kéde ìpèníjà tó ń kojú lásìkò ọjọ́ ìbí rẹ̀

N kò sùn dáadáa fún ọjọ́ mẹ́rin, mo lọ sápamọ́ láti sùn, ni Olorì wà ji mi fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí - Ooni

Aworan Ooni of Ife

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun osu Kẹwa ni Ọọni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, pe ẹni ọdun mejidinlaaad́ọta laye.

Ọpọ awọn eeyan, paapa julọ awọn ayaba laafin ni wọn si tu si ori ayelujara lati kan saara si Ọba alaye naa lori ayẹyẹ ọjọbi rẹ ọhun.

Ọba Ogunwusi lasiko to n sọrọ lori ayẹyẹ ọjọ ibi naa salaye bi olori tuntun, Ayaba Mariam Ajibola Anako Ogunwusi, se wa gbe oun jade lẹyin ti oun ti lọ sapamọ lati lọ sun.

Kabiyesi ni o ti to bi ọjọ mẹrin ti oun ko ti ni anfani lati sun oorun asunfọnfọn sugbọn ni kete ti olori naa wa ke si oun, ni agbara de si oun lara.

“N ko ro pe mo ti i sun oorun asunfọnfọn fun ibi ọjọ mẹrin, n ko si mọ pe mo le ṣe ayẹyẹ yii nitori mo ti lọ sa pamọ si ibi kan lati sun.

“Ati pe wọn ti gbe mi ni lamba, mo wa bẹẹ wọn pe ki wọn jẹ ki n sun fun bii iṣeju mẹwaa.

“Nibi ti mo ti n rẹju ni olori ti wa ba mi pe ero ti pọ nita. Mo ni o yẹ ki sun ni, iwọ naa tun wa ji mi bayi.

“Sugbọn nkankan wa fun ni agbara lati yọju si awọn ero to wa nita.

Kete ti mo fi oju kan awọn ero ni agbara de si mi lara , ti mo si le ṣe ayẹyẹ naa mọjumọ.”

Ọọni wa dupẹ lọwọ awọn ogunlọgọ awọn eeyan ti wọn tu sita lati wa yẹ si lọjọ ibi rẹ, o gbaladura pe ki ọlọrun duro ti onikaluku wọn.

Lara awọn to wa ni bi ayẹyẹ naa naa, Ayaba Mariam Ajibola Anako Ogunwusi, Ọmọọba Toyin Kolade ati awọn Ọba Alade miiran.

Aworan Ooni, Olori ati Iyalaje

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ọọ̀ni ń ṣe ọjọ́ ìbí, àwọn olorì ń kọlu ara wọn láti kí i kú oríire

Ooni Ogunwusi atawọn Olori rẹ

Oni ni ọjọ ibi Ọba alayeluwa, Ọọni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, pe ẹni ọdun mejidilaaad́ọta laye, ti pupọ awọn eeyan si ti tu si ori ayelujara lati kansari si Ọba lori ayẹyẹ ọjọbi naa.

Ọpọ eeyan si lo ti n ki Ọọni lori ayelujara ku oriire ọjọ ibi naa eyi ti ko yọ awọn olori tuntun lafin ati awọn eeyan jankanjankan miiran silẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, ayaba mẹrin lo ti wọnu aafin Ọọni Ile Ife laarin osu meji, to si se iyawo alarinrin fun ikọọkan wọn.

Orukọ awọn olori naa ni Ayaba Mariam Ajibola Anako Ogunwusi, Olori Elizabeth Ogunwusi, Olori Tobi Phillips Ogunwusi ati Ayaba Ashley Ogunwusi.

Awn olori mẹrẹẹrin naa si lo n ki Kabiyesi ni mẹsan mẹwa lori ayelujara pe o ku ayẹyẹ ọdun orikadun to n se.

Ooni ati Olori Mariam

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ọọni ko ni ri ibanujẹ lyin to fẹ awn olori tuntun - Mariam Ogunwusi

Olori Mariam Ajibola Anako Ogunwusi, ninu fọnran kan to wa lori ayelujara lo ti kulẹ siwaju Ọọni.

Bẹẹ lo n sadura pe ki Ọba alayeluwa naa pẹ lori apere ninu alaafia ati ifọkanbalẹ.

Ayaba ni Ọọni ko ni ri ibanujẹ lẹyin to ti fẹ awọn iyawo tuntun naa, ki Ọlọrun si jogun ẹmi gungun ati alaafia fun pẹlu.

O wa sapejuwe Ọọni gẹgẹ bi ọkọ to nifẹ iyawo ati mọlebi ni apapọ, to si fẹ ilọsiwaju ilẹ Yoruba ati orilẹede Naijiria ni apapọ.

Ooni ati Olori Mariam

Akande mi, Ajiwẹ fun Ooṣa, o ti fi han mi bo se jẹ eeyan daadaa si - Olori Ashley Ogunwusi

Olri Ashley ati Ooni

Oríṣun àwòrán, hrhashleyafolasade/Instagram

Ayaba Ashley Adegoke Ogunwusi sapejuwe bi Ọọni se jẹ akikanju ọkunrin to nifẹ si pupọ, to si duro ti oun nigba isoro.

O wa gbadura pe ki Ọba alayeluwa naa pẹ laye, ki Ọlọrun si fun ni agbara lati bori awọn isoro ati lati gbe ilẹ Yoruba lọ si ibi giga.

Pẹlu oriki ni Ayaba Ashley fi ki Ọọni ti Ile Ife loju opo Instagram rẹ.

"Inu mi dun pe o se ayẹyẹ ọjọ ibi mii, Akande mi, Ajiwẹ fun Ooṣa, o ti fi han mi bo se jẹ eeyan daadaa si.

Mo gbadura pe Olodumare yoo tubọ maa fun ọ ni agbara lati koju ipenija ti aye ba fi koju rẹ.

Omo Erin gangan Ile, Omo Erin gangan Ode, Adimula Erujeje, Olewalowo, Dagunduro Oko ODU, Ekun ton fin tori tori, Ekun ton fin tiru tiru"

Ohun ti Olori Ashley fi soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, hrhashleyafolasade/Instagram

Ibẹrẹ ohun ọtun ni ọna ara, ni ọjọ ibi naa jẹ fun Ọọni - Olori Tobi Phillips Ogunwusi

Bakan an ni Ayaba Tobi Phillips Ogunwusi naa ti kan sara si ọkọ rẹ, Ọọni Adeyeye Ogunwusi lori ayelujara loni ọjọbi rẹ.

Ninu fidio ti Olori Tobi fisita ati ọrọ to kọ tẹle, Ayaba naa ni ibẹrẹ ohun ọtun ni ọna ara, ni ọjọ ibi naa jẹ fun Ọọni.

O wa gbadura pe ki Ọba pẹ laye ninu alaafia ati ifọkanbalẹ.

Aworan lati ori ayelujara

Oríṣun àwòrán, instagram.com/hrm_queentobiphillips_ogunwusi/