Iná, èéfín àti ìrò ìbọn gbalẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Iran

eefin to n ru ni Ọgba ẹwọn ni Iran

Oríṣun àwòrán, TWITTER/VAHID ONLINE

Ina alagbara ti sọ lọjọ Satide ni gbajugbaja ọgba ẹwọn Evin ro wa ni orilẹede Iran.

Ọgba ẹwọn yii ni wọn maa n ko awọn akọroyin, ọmọ ilẹ okeere atawọn oloselu nla ti wọn ba ni ko lọ se ẹwọn si.

Ninu awọn fidio ti wọn sọ soju ayelujara lo safihan eefin ati ina nla ladugbo ti ọgba ẹwọn naa wa nilu Tehran.

Bakan naa ni iro ibọn ati ibugbamu n waye ninu ọgba ẹwọn naa.

Bi o tilẹjẹ pe awọn osisẹ ọgba naa ni ko sewu, awọn to n se akoso isẹlẹ naa maọ awọn fidio to wa lori ayelujara safihan pe iro ibọn naa si n tẹsiwaju.

Bẹẹ ba gbagbe, aimọye ọsẹ ni idarudapọ ti n waye lorilẹede Iran nitori iwọde tawọn eeyan to tako ijọba n se lori iku obinrin kan.

Obinrin naa, Mahsa Amini ni wọn sọ pe awọn ọlọpaa orilẹede naa na titi to fi daku, to si papa gbe ẹmi mi nitori ko lo ibori Hijab.

Eeyan mẹjọ fara pa ninu isẹlẹ ina ati ibọn yinyin naa - IRNA

Amọ akọroyin BBC ko ti le fidi rẹ mulẹ boya rogbodiyan ọgba ẹwọn naa ni nnkan se pẹlu iwọde to n waye lori lilo Hijab lorilẹede Iran.

Amọ eyi le ri bẹẹ nitori ọpọlọpọ awọn oluwọde nijọba Iran ti sọ si ọgba ẹwọn Evin naa.

Gẹgẹ bi ileesẹ iroyin ijọba nilẹ naa, IRNA ti wi, eeyan mẹjọ lo ti fara pa ninu isẹlẹ ina ati ibọn yinyin naa.

Nigba to n sọrọ latinu ọgba ẹwọn naa, Gomina ipinlẹ Tehran sọ lori ẹrọ amohunmaworan ijọba pe ifẹhonuhan lo waye nibẹ.

O ni apa kan ninu ọgba ẹwọn ọhun ti wọn ko awọn ọdaran ke ke ke si ni wọn ti se ifẹhonuhan to lọwọ jagidijagan ninu, awọn si ki bomi pana isẹlẹ naa.

Amọ ninu awọn fidio ti wọn sọ sori ayelujara naa la ti ri pe ibọn n dun lakọkọ, ti ina ati eefin si gba ilẹ kan.

Koda, ọpọ eeyan to wa nita ọgba ẹwọn naa ni wọn n pariwo pe “Iku ni fun aarẹ apasẹ waa’.

Ọrọ yii si ni akọmọna awọn eeyan to n se iwọde lorilẹede Iran.

Wọn kọ oruk obinrin to ku eyi to se okunfa iwọde ni Iran sori ilẹ

Oríṣun àwòrán, SHUTTERSTOCK

Aworan awọn ẹlẹwọn wa to wa lori orule ọgba ẹwọn jade sori ayelujara

Bakan naa ni fidio kan se afihan ohun kan to n yinbọn mọ ọgba ẹwọn ọhun, ti ibugbamu si waye.

Ogunlọgọ eeyan lo duro siwaju ọgba ẹwọn naa, ti ko si si lilọ bibọ eeyan ati ọkọ, tawọn ọlọpa apẹtusaawọ si n wọnu ọgba ẹwọn ọhun.

Bi o til jẹ pe awọn alasẹ ijọba ni ohun gbogbo ti pada bọ sipo nipa isẹlẹ naa amọ awọn fidio ti wọn si n ju sori ayelujara lo n safihan pe ina naa si n jo lọ, ti iro ibọn si tun n dun.

Bakan naa ni aworan awọn ẹlẹwọn wa to wa lori orule ọgba ẹwọn naa jade sori ayelujara, ni abala igun ti wọn ko awọn ẹlẹwọn nipasẹ oselu si atawọn oluwọde pẹlu.

Awọn mọlẹbi awọn ẹlẹwọn naa sọ fun BBC pe awọn ko tii le kan sawọn ẹbi awọn lori foonu, gẹgẹ bawọn se maa n se tẹlẹ.

Wọn ni o dabi pe wọn ti ge awọn oju opo itakun agbaye to so mọ ọgba ẹwọn naa.