Olorì Ashley darapọ̀ mọ́ àwọn Olorí l'Áàfin Ooni Ogunwusi, kà nípa ohun tó bá nilẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
"Mo dupẹ pupọ lọwọ gbogbo ẹbi Ogunwusi pe ẹ ti wa gba mi gẹgẹ bi ọmọ yin bayii".
Gẹgẹ bi Ooni ti Ile Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi Ojaja Keji tun ti ṣara gija gbe iyawo kẹrin wọ ọọdẹ rẹ laarin Oṣu kan, igboro ti kun fun ẹjọ.
Lẹyin ti ooni fẹ Olori Tobiloba Phillips ni ọjọ Kẹsan Oṣu Kẹwa, ko ju ọsẹ kan sirawọn ni Olori Ashley naa fi ẹsẹ osun wọ ile Ọba.
Bi ẹ ko ba gbagbe, iroyin kan kaakiri pe Ooni gbe iyawo keji rẹ niṣu lọka , Olori Elizabeth ni ọjọ Kẹjọ Oṣu Kẹsan ọdun 2022 yii kan naa ti ko ju wakati melo kan ti o ṣẹṣẹ fẹ Olori Mariam Anako.
Fidio mii tun ṣafihan bi awọn idile Ooni ti Ile Ife ṣe tẹwọ gba Folashade Ashley ọmọ Adegoke gẹgẹ bi iyawo wọn to si jẹ pe Baba Ooni lo dari idle naa.
Ninu fidio kan to jade sori ayelujara ti o ti n dupẹ lọwọ gbogbo awọn to wa sibi igbeyawo naa, o jẹwọ ọmọ yoruba to jẹ doju ami.
“Mi o wa ni le gbe ẹrọ gbohun gbohun silẹ ki n ma ki ỌkỌ, mi, Ooni ti Ife, Ooniriṣa, Ooni ti Ilẹ Ife, Arole Oodua...”

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Bakan naa ni Oloori Ashley tun fi ohun idupẹ rẹ ranṣẹ si awọn idile tirẹ ti wọn wa yẹẹ si nibi igbeyawo rẹ.
Olori Ashley to kunlẹ to si ni oun fẹ foribalẹ fun ẹgbọn Ooni ti Ife. “Wọ́n ni baba ku, baba kù ni, mo dupẹ lọwọ baba mi tuntun, Ọmọọba Aderopo Ogunwusi pe ẹ ku aduroti mi, ẹ ku adura yin lori mi, inu mi dun gan lati wa di ọmọ yin bayii. Ifẹ tẹẹ ni si mi ko ni ku o."
Koda, Olori Ashley tun kẹnu bọ ọrọ o mu oriki iya Ooni ti Ife to si kii dele dele to ni lootọ iya ti dagbere faye amọ awọn gbudọ ranti rẹ.
Gbogbo awọn Olori agba, ẹgbọn Ọba lọkunrin ati lobinrin to ba l’Aafin lo tẹriba tabi kunlẹ ki kaakiri.
Pẹlu ọrọ ẹnu rẹ, o fi ye yekeyeke pe kii ṣe eeyan kan ti wọn ṣẹṣẹ mu wọ inu Aafin bikoṣe ẹni to ti n ba wọn gbe l’Aafin daadaa.

Oríṣun àwòrán, Olori Ashley Instagram
Ki lo ṣẹlẹ ti Ooni fi n ko Olori jọ lera lera?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọpọlọpọ eeyan lo ti n woo pe ki ni Oriade yii ri to fi n fẹ awọn Olori ni ọjọ ati ọsẹ ti ko pẹ sira wọn rara.
Ko si ẹni to lee fidi eyi mulẹ tori pe ninu Aṣa ilẹ Yoruba, Ọba alade ni gbogbo ẹtọ ati aṣẹ lati fẹ iye iyawo to ba wu u koda o lee gbẹsẹ le obinrin to ba wu u.
Ṣaaju gbogbo saa iyawo fifẹ yii, Ooni ti Ile Ife ti ṣe igbeyawo sẹyin nigba ti ko tii jẹ Ọba pẹlu Adebukola Bombata amọ ọrọ wọn ko wọ. Bakan naaOoni fẹ ọmọ
Edo kan, Zainab-Otiti Obanor ohun si lo gbe wọ Aafin nigba naa gẹgẹ bii aya oye amọ igbeyawo naa ko ju Oṣu mẹtadinlogun lọ ti wọn fi pinya.
Ni ọdun 2018 ni Ooniriṣa fẹ Silekunola Naomi gẹgẹ bi Olori to si bi ọmọ ọkunrin fun Ooni amọ ni ọdun to kọja ninu oṣu Kejila ni Olori Naomi kede faraye pe igbeyawo oun ati Ooni ti daru.
Ohun to yẹ koo mọ nipa Olori tuntun Folashade Ashley

Oríṣun àwòrán, Olori Ashley Instagram
- Ọmọ bibi ilu Ile Ife ni Ashley naa gẹgẹ bii Ooni to si mọ ile daadaa ati itan aṣa ilu Ife.
- Akọṣẹmọṣẹ ninu imọ iṣiro owo ni Olori Ashley.
- Ashley kẹkọ gboye Masters ninu imọ ẹkọ Iṣiro owo ati eto isuna ni fasiti Greenwich to si tun ni okoowo to n ṣe ni ilẹ UK.
- O ni ileeṣẹ ti ara rẹ to jẹ adari fun. Ajọ ti ko dara le ijọba to fi n tọju awọn ọmọde ti ko rọwọ họri ati opó.













