Onítíàtà, ẹ tún ààrọ̀ yín ṣe, kẹ́ yé tọ̀rọ̀ owó kiri tí àìsàn bá dé lọ́jọ́ alẹ́ - Toyin Aṣẹ́wó tó re Mecca
Toyin Adegbola: Ó yẹ káwọn onítíátà pọnmi sílẹ̀ de òùngbẹ torí ọjọ́ alẹ̀

Gbajumọ osere tiata lobinrin, Yeye Oluwatoyin Adegbola, ti ọpọ eeyan mọ si Toyin Asẹwo to re Mecca ti foju abuku wo asa kawọn onitiata maa tọrọ owo lasiko aisan.
Adegbola, ẹni to gbalejo BBC Yoruba sọrọ ni ẹkunrẹrẹ nipa itan aye rẹ, ibi to ba igbe aye rẹ de ati isẹ tiata lapapọ.
Nigba to n tara poro lori asa to gbode kan, nibi ti wọn ti maa n tọrọ owo fawọn osere tiata to ba n saisan, Adegbola ni eyi ko bojumu rara.
Gbajumọ osere naa wa woye pe se lo yẹ kawọn osere tiata se ọmọ ti wọn ba bi ni iwọn eku ni iwọn itẹ, ki wọn ma si da omi ju iyẹfun lọ.
"Asilo anfaani lọdọ araalu ni ki osere tiata maa tọrọ owo lọwọ wọn"
O woye pe bi eeyan ko ba tọju ọmọ lasiko to wa ni opepe, tabi to bimọ ju eyi ti agbara rẹ le tọju lọ, awọn ọmọ naa le ma yege lati tọju onitọun lọjọ alẹ.
Bakan naa lo gba awọn osere tiata lọkunrin nimọran pe ki wọn yee fẹ ọpọ iyawo lasiko ti okiki wọn ba n tan, nitori alaafia wọn lọjọ alẹ.
Adegbola wa woye pe asa ki awọn osere tiata maa bọ sori ayelujara lati tọrọ owo lasiko ti aisan ba de lọjọ alẹ lọwọ awọn ololufẹ wọn kii se iwa to bojumu.
O ni gbogbo eeyan lo ni ohun to n la kọja, bi igba ti eeyan si n si anfaani to ni lo ni, tawọn onitiata to n saisan ba n tọrọ owo lọwọ awọn ololufẹ wọn.
O fikun pe kii se awọn osere tiata nikan ni osisẹ mto wa lawujọ, bẹẹ si ni awọn agbaagba miran naa n se aisan lai jẹ pe wọn wa sojutaye lati bẹbẹ fun owo.
Asẹwo to re Mecca wa rọ awọn akẹẹgbẹ rẹ lagbo tiata lati maa pọn omi silẹ de oungbẹ nitori ọjọ alẹ, ki wọn si jawọ ninu sise agbe lasiko ti aisan ba de lọjọ alẹ.






