N kò gbà pé omi ló wọ́ ọmọ mi lọ, wọ́n pa á ni - Bàbá Daniel

Àkọlé fídíò, Daniel Ayoola: Bàbá olóògbé ní àwọn tó pa ọmọ òun ló wá ha mọ́ ojú àgbàrá tí kò gba ewúrẹ́
N kò gbà pé omi ló wọ́ ọmọ mi lọ, wọ́n pa á ni - Bàbá Daniel

Bàbá Daniel ní ẹ̀jẹ̀ ti gbẹ lára ìyá rẹ̀, láti ọjọ́ tọ́mọ rẹ̀ ti sọnù ló ti dùbúlẹ̀ àìsàn

Daniel Ayoola

Adura ti obi maa n gba ni pe ko ma fi ọwọ rẹ gbe ọmọ sin tabi ki ọmọ rẹ mase rn arinra.

Amọ isẹlẹ kan to waye ni adugbo Wakajaye nilu Ibadan, nigba ti ọmọ ọdun mẹwa di awati, ko to di pe wọn ri oku rẹ lẹyin ọjọ kẹrin, ti gba omi loju awọn obi rẹ.

Nigba ti BBC se abẹwo si adugbo naa, nibi ti wọn ti ri oku ọmọ ọhun, se la ri ero rẹpẹtẹ to pe sibẹ lati wo oku ọmọ naa, to ti n run.

Bi o tilẹ jẹ pe ko si ẹnikẹni to le sọ bi oku naa se de oju agbara ti wọn ti ri amọ baba ọmọ naa ni wọn sẹsẹ gbe oku naa sọ sadugbo ọhun ni.

Wọn kọkọ sọ fun mi pe Tisa kan lo ran Daniel nisẹ nigba ta n wa – Michael Ayoola

Nigba to n fi tomije-tomije salaye bi isẹlẹ naa se waye, Michael Ayoola, tii se baba Daniel ni ile ẹkọ ni ọmọ oun lọ, ti ko si pada wale mọ.

O ni gbogbo iyanju awọn lati se awari rẹ lo ja si pabo, ti ile ẹkọ rẹ si n sọ oniruuru ọna ti ọmọ naa gba rin.

O ni wọn kọkọ sọ fun awọn pe Tisa kan lo ran nisẹ, nigba to ya, wọn tun sọ fun awọn pe oun ati akẹkọọ mẹrin kan ni wọn dijọ ran nisẹ.

O fikun pe lọjọ ti awọn ẹbi oun digun lọ ba awọn ọga ile ẹkọ naa, ni awọn ri oku rẹ lọwọ irọlẹ.

“Ẹjẹ ti gbẹ lara iya Daniel, ko le rin, ko si le sọrọ, o wa lori aisan lati ọjọ ti ọmọ rẹ ti sọnu”

Nigba to n salaye ohun ti oju wọn ti ri lati igba ti Daniel ti di awati, baba oloogbe naa ni iya ọmọ naa ni ẹjẹ ti gbẹ lara rẹ.

O ni lati ọjọ ti wọn ti n wa Daniel ni iya rẹ ti dubulẹ aisan, laile le sọrọ tabi rin nitori aarẹ ọmọ to mu.

Baba Daniel fikun pe awọn eeyan kan lo pe oun pe wọn ti ri oku ọmọ naa loju agbara, pe agbara lo wọ lọ.

Amọ o ni wọn pa ọmọ oun ni, ti awọn eeyan kan si sọ fun oun pe awọn eeyan mẹrin kan lo gbe Daniel lọ.

“Oju agbara ta ti ri oku Daniel kere pupọ, ko le gba ẹran gan debi ọmọ ọdun mẹwa, o si nira lati fa oku rẹ yọ”

Baba Daniel tun salaye pe oju gọta kan nibi tawọn ti gba kọja tẹlẹ, ni wọn ha oku ọmọ oun mọ, eyi to kere pupọ lati gba oku rẹ.

O ni awọn to pa ọmọ naa mọọmọ ha oku rẹ soju agbara naa ni, o si nira fun awn pupọ lati fa oku ọmọ naa jade loju agbara kekere naa.

Bakan naa lo wa n kọminu pe bawo ni agbara se maa gbe odidi ọmọ lọ, ti agbara naa ko si gbe bata ẹsẹ rẹ ati apo iwe iwe rẹ lọ?

“Ijọba ẹ tete sawari awọn onisẹ ibi to n ji eeyan gbe pa nitori a ko mọ ẹni to kan”

Baba Daniel, ẹni to n sọkun kikoro nitori iku ọmọ rẹ naa wa n rawọ ẹbẹ sawọn agbofinro ati ijọba lati ba oun se awari awọn olubi ẹda to da ẹmi ọmọ oun legbodo.

Michael Ayoola ni oun n fẹ idajọ ododo lori isẹlẹ naa nitori ewu nla gidi ni eyi jẹ, ti ko si sẹni to le sọ ẹni ti iru isẹlẹ lee kan lọjọ ọla.

Ẹgbọn Daniel ati alabagbele wọn to ba BBC Yoruba sọrọ naa jẹri si pe ọmọ daadaa ni Daniel Ayoola, kii rin irinkurin, to si niwa irẹlẹ ati ọyaya.