Ikọ̀ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Amẹrika, FBI, ló gbé òkú àbúrò mi lọ sin lọ́dọ̀ wọn - Ayorinde Owolabi

"Gbígbé òkú Olugbenga Owolabi lọ Amẹ́ríkà ní ohun ṣe pẹ̀lú òmìnira Yorùbá"

Olugbenga Owolabi

Oríṣun àwòrán, Delta Newsroom

Ayorinde Owolabi, to jẹ ẹgbọn Olugbenga Owolabi ti awọn afurasi darandaran kan ji gbe, ti wọn tun ṣekupa niluu Ogbomoso ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ti sin oku rẹ.

Ayọrinde, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe ijọba Amẹrika funra rẹ lo gbe oku oloogbe naa lọ lati sin.

Ṣaaju ni awọn afurasi darandaran naa ti kọkọ ji oloogbe naa ati oṣiṣẹ rẹ kan, Racheal Opadele gbe niluu Ogbomoso, ki wọn to gbẹmi rẹ.

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan an ni wọn ṣekupa ọkunrin naa, to fi mọ ọlọkada to gbe awọn ẹbi rẹ lọ gbe owo fawọn ajinigbe naa.

Olugbenga, to jẹ ọmọ onilu nilẹ Amẹrika lo da ile itura kan silẹ niluu Ogbomoso, ki iṣẹlẹ laabi naa to ṣẹlẹ.

"Awọn FBI lo wa gbe oku aburo mi lọ Amẹrika"

Ayorinde Owolabi ṣalaye fun BBC Yoruba pe opin ọsẹ to kọja ni wọn sin oku ọkunrin ọhun niluu Maryland, l’Amẹrika.

O ṣalaye pe ijọba Amẹrika lo sọ pe ki wọn gbe oku ọkunrin naa wa fun iwadii ni kikun, nipa ohun to ṣokunfa iku rẹ ati fun aabo awọn mọlẹbi rẹ.

O ni “Kii ṣe pe tori pe o jẹ ọmọ onilẹ lọhun, ni wọn ṣe ni ki wọn gbe oku rẹ lọ.”

“Wọn sọ fun mi pe ti a ba ni ki a sin oku naa nibi, ti awọn ọmọ rẹ atawọn ọrẹ wọn wa sile, ti awọn ajinigbe yẹn ba tun wa ji wọn gbe nkọ?.”

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Olugbenga Owolabi: Àbúrò olóògbé ní wọ́n gbé òkú náà bíi ẹ̀rí pé wọn ń pa Yorùbé láìtọ́

"Banji Akintoye ati Sunday Igboho fọwọsi pe ki FBI maa gbe oku aburo mi lọ"

Ayorinde tẹsiwaju pe “Wọn ni wọn maa fun mi ni ‘assylum’ amọ mo ni mi o fẹ, pe iran Yoruba ni ki wọn yọ ninu ọfin.”

“Mo dẹ ba baba Akintoye sọrọ, ati Sunday Igboho, wọn dẹ ni ki a gba ki wọn gbe oku rẹ lọ.”

Ayorinde ṣalaye siwaju si pe awọn akọsẹmọṣẹ oniṣegun lati ilẹ Amẹrika lo ṣe ayẹwo oku oloogbe naa.

O ni wọn yẹ oku na wo niluu Ogbomoso, lẹyin naa ni wọn gbe lọ sile iwosan kan niluu Deleware, nibi ti wọn tun ti ṣe ayẹwo mii.

Ọkunrin naa ni ijọba Amẹrika fi da awọn loju pe awọn afurasi ajinigbe lo ṣe ikọlu naa, amọ ijọba Naijiria ko tii ṣe ohunkohun nipa rẹ.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii ni wọn sin oku oloogbe naa nile ijọsin Trinity Life Church, to wa ni Maryland, l’Amẹrika.