Mọ̀lẹ́bi mẹ́rin fi ẹ̀gẹ́ tí wọn fi ṣe Fùfú kù, ro láfún jẹ, ikú bá dé

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Awọn mọlẹbi mẹrin ninu idile kan ti ku lẹyin ti wọn jẹ amala ni ijọba ibilẹ Mopa Muro, ni ipinlẹ Kogi.
Arakunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Pa Motilewa, iyawo rẹ, ọmọbinrin rẹ meji ati ibatan rẹ kan ni wọn jẹ amala ti nkan si daru.
Iwadii ni ẹgẹ ti wọn fi ṣe fufu ku, ni wn sọ di Láfún lati fi ro amala ti wọn jẹ, ki ara to bẹrẹ si ni wọn ni oru.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni oru ni iṣẹlẹ naa bẹrẹ, ti awọn eniyan si gbiyanju lati tọju wọn.
Amọ ọmọ to kere ju ninu ile naa ku ni Ọjọ Ẹti, ti mọlẹbi wọn naa tun gbẹmi mi ki wọn to tun gbe wọn lọ si ileewosan miran ni Egbe.
Bakan naa ni ọmọbinrin agba ti wọn pe orukọ rẹ ni Mosun ku ni Ọjọ Aiku, ki baba wọn naa to ku ni ọmọ kan naa.
Iya ile ti wọn pe orukọ rẹ ni Molomo nikan lo ṣi wa laye, ti awọn dokita si n tiraka lati doola ẹmi rẹ.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Amọ titi di asiko yii, wọn ko tii le sọ boya amala ọhun ti wọn jẹ lo ṣekupa wọn.
Bakan naa ni kọmiṣọnna fun eto iroyin nipinlẹ Kogi ti ṣabẹwo ibanikẹdun si aafin ọba Elulu, ti ijọba ibilẹ Mopa lati ṣoju gomina Yahaya Bello.
Kọmiṣọnna naa ni iṣẹlẹ naa jẹ ibanujẹ ọkan fun gomina naa, ti yoo si sa gbogbo ipa rẹ lati ri pe iwadii otitọ waye lori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni gomina ti paṣẹ ki ẹka eto aabo ati ilera ri pe iwadii naa sọ koko ohun to ṣekupa mọlẹbi naa.















